Olùdìbò 2,327 ló péjú fún yíyàn Asoju APC fún Gómìnà Ekìtì

Àkọlé àwòrán Ètò ìdìbò tí bẹ̀rẹ̀ ní pẹrẹwu ni Ìpínlẹ̀ Ekiti tí kò sì sí wàhálà tàbí ewu

Eto ìdìbò tí bèrè ni pẹrẹwu ni Ìpínlẹ̀ Ekiti tí kò sì sí wàhálà tàbí ewu.

Ìròyìn fi tó wà leti gbogbo àwọn akopa lo tí kókó dibò tí wọn láti yan ẹniti yoo ṣojú ẹgbẹ́ òṣèlú APC fún ipò Gómìnà tí yóò wáyé, àwọn Gómìnà àná méjèèjì Ṣẹ́gun Òní àti Káyọ̀dé Fayemi wà nínú ìdíje náà.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionOlùdìbo 2,327 ló péjú fún yíyàn Asojú APC fún ìdíje Gómìnà l'Ekìtì

wọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Gómìnà Ìpínlẹ̀ Òndó nígbà kan Bamidele Olumilua àti Nìyí Adebayo lo soju àwọn oludibo egberun méjì lè Okooleloodunrun lè méje to wá fún ìdìbò náà. Komisona olopaa nipínlẹ̀ Ekiti Ahmed Bello, Oga agba awon otelemuye àti ogunlogo awon eleto ààbò lo peju síbi ètò ìdìbò náà, nítorí àti dekun ìwà jagidi jagan to le bẹ silẹ nibe.

Àkọlé àwòrán Gbogbo òṣìṣẹ́ elétò àbò síbi ètò ìdìbò yíyàn Asoju APC fún ìdíje Gómìnà l'Ekìtì

À wọn akópa sàlàyé pe etò ìdìbò náà ń lọ ní ìrọwọ́rọsẹ̀, bákan náà ló yàtò gédégédé sí irú èyí tó wáyé lọ́sẹ̀ tó kọjá.