Èkìtì: Kayọde Fayẹ̀mi ni yóò ṣojú APC nínú ìbò gómìnà

Image copyright Kayode Fayemi
Àkọlé àwòrán Òjìlélẹ́ẹ̀dẹ́gbẹ̀rún lé ẹyọ kan, 941, ìbò ni Fayẹmi nínú ètò ìdìbò naa

Mínísítà fún ìdàgbàsókè ìwakùsà àti ìrin rírọ́ ní Nàìjíríà, Kayọde Fayẹmi ló jáwé olúborí níbi ètò ìdìbò abẹ́lé ẹgbẹ́ òṣèlú APC tó wáyé l'Ékìtì lọ́jọ́ Àbámẹ́ta.

Fayẹmi ni òjìlélẹ́ẹ̀dẹ́gbẹ̀rún lé ẹyọ kan ìbò, 941, nígbà tí Ṣẹgun Oni tó ṣe ipò kejì ni ọ̀rìnlénírinwó lé ẹyọkan ìbò.

Òun ni yóò díje dupò gómínà lábẹ́ àbùradà ẹgbẹ́ All Progressives Congress, APC, nínú ètò ìdìbò sí ipò gómìnà tí yóò wáyé ní ìpínlẹ̀ Èkìtì lọjọ́ kẹrìnlá, oṣù Keje, 2018.

Olùdíje mẹ́tàlélọ́gbọ́n ló kópa ninú ètò ìdìbò nàá.

Lára wọn lati rí gómìnà àná ní ìpínlẹ̀ nàá, Ṣẹgun Oni.