Ọmọogun Congo: a ti sàwárí àwọn tí wọn jígbé

Àwòràn Virunga National Park Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Àwọn Bìrìtìkó òhún rìnrìn àjò afẹ́ lọ sí Virunga National Park ní wọn fi jí wọn gbé

Wọn ti kéde rírí àwọn bìrìtìkó méjì tí wọn jí gbé lásìkò tí wọn rìnrìn àjò afẹ́ lọ sí orílẹ̀-èdè DR Congo lọ́jọ́ Etì tó kọja ní Kinshasa.

Akòwé ilẹ̀ òkèrè Boris Johnson ló kéde ọ̀rọ̀ òhún lọ́sàn òní sàlàyé pé, àwọn tó jí wọn gbẹ ọ̀hún ló tú wọn sílẹ̀.

wọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Sáájú àkókò yìí ní agbẹnusọ fún àwọn ọmọogun orílẹ̀-èdè DR Congo ti sọ pé àwọn kò ní simi àfi tí wọn bá di àwárí.

Àwọn eniyan Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Àwọn Bìrìtìkó òhún rìnrìn àjò afẹ́ lọ sí Virunga National Park ní wọn fi jí wọn gbé

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò tìí sí ọ̀rọ̀ kankan láti ọ̀dọ̀ ìjọba, àwọn ọmọ ogun DR Congo ti sàwárí àwọn ọmọ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì tí wọn jígbé.

Àwọn òṣìṣẹ́ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì dúpẹ́ lọ́wọ́ ìjọba DR Congo fún akitiyan wọn láti sàwárí àwọn tí wọn jí gbé, bákan náà ní wọn kí àwọn ẹbí Rachel Makissa Baraka tó pàdánù èmí rẹ̀ lásìkò ìjínigbé òhún.

A kò tí mọ orúkọ àwọn tí ìṣẹ̀lẹ̀ nàá ṣẹ̀ sí sùgbọn ìròyìn tó tẹ BBC Yorùbá lọ́wọ́ sọ pé wọn ń gba ìtójú ní ilé ìwòsàn.