Ọlọ́pàá mu afẹ̀sùnkan ti wọn pè ni ọgá awọn ajínigbé

Barau Ibrahim ti a fẹsun kan pe o je ogboju ajinigbe ati apaniyan Image copyright NIGERIA POLICE
Àkọlé àwòrán Àwọn ọlọpàá gba ibọn méjì ati ọta mọ́kànlélàádọ́ta lọ́wọ́ Barau

Ọwọ́ àwọn ọlọpàá ti tẹ ọ̀gbẹ́ni kan Barau Ibrahim, tí wọn f'ẹ́sùn kan pé o jẹ́ ògbójú ajínigbé àti apàniyàn ti oun da Birnin Gwari ni Ipinlẹ̀ Kaduna, òpópónà Abuja si Kano àti Ìpìnlẹ̀ Zamfara rú.

Ọga ọlọ́pàá tí oun dari ẹ̀ka asèwádìí ile iṣẹ́ ọlọ́paa tí a mọ si IRT Abba Kyari sọ wipe 'Rambo' ni wọ́n ń pe Barau ni awọn agbegbe ti o ti n ṣọṣẹ́ látàri bo ṣe máa ń lo ibọn AK47 meji lẹ́ẹ̀kan náà.

Afẹ̀sunkan náà ni àwọn ọlọpàá gba ibọn méjì ati ọta mọ́kànlélàádọ́ta l'ọwọ rẹ̀ nígba tí wọn ràa mú ni ọ̀san ọjọ́ Àìkú ní Maraban Yakawada, Ipínlẹ̀ Kaduna.

Ọ̀rọ̀ gbina, ó ti ń ràn nítori àwọn ọmọ Yahoo

Bákan náà ni ikọ̀ IRT mú éni ogójì ọdún kan Shehu Abdullahi tí wọ́n pe ní ọ̀kan lára awọn ọmọlẹ́yìn Barau.

Ni bayìí, Kyari ni àwọn n ṣiṣẹ́ takuntakun láti fi pàǹpẹ́ mú awọn tó kù lara ọmọ ẹgbẹ́ Barau to ti bẹ́ lù 'gbẹ́.

Ẹ ó rántí wípe ikọ̀ IRT ni o mú afẹsùnkan Chukwudi Onuamadike tí ọ̀pọ̀ eniyan mọ̀ sí Evans ní ọdún tó kọja lórí ẹ̀sùn pé oun lo sagbátẹrù ìjínigbe tí ó burú jù ní orilẹ̀èdè Naijiria.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí: