Ìkọlù Indonesia: Ẹbí ẹlẹ́ni mẹ́fà pa ènìyàn 13 ni ilé ìjọ́sìn

Òṣiṣẹ́ kan ni ibi tí adó olóró náà ti bu ní iwájú ilé ijosin kan ní Indonesia Image copyright EPA
Àkọlé àwòrán Awọn òṣiṣẹ́ ní iwájú ilé ìjọsin níbi tí adó olóró náà ti bú ní Indonesia

Bàbá, ìyá àti àwọn ọmọ wọn mẹ́rin ni ó ṣe ìkọlu pẹ́lú àdó olóró sí ilé ìjọ́sìn mẹ́ta ní Indonesia nibi tí ènìyàn mẹ́tàlá ti gbẹ́mìí mì, àwọn ọlọpàá ilẹ̀ náà lo sọ bẹ́ẹ̀.

Ọ̀ga ọlọpáà orilẹ̀ èdè náà Tito Karnavian ní idilé náà tí ó jẹ́ ọmọlẹ́yin ẹgbẹ Islamic State ni ó de adó oloro mọ́'ra wọn tí wọ́n sì lọ ṣe ìkọlù kákàkiri ilú Surabaya.

Ẹgbẹ́ agbésùnmọ̀mí Islamic State ti kéde pé àwọn mọ̀ nipa ìkọlù náà.

Image copyright Reuters
Àkọlé àwòrán Ọlọpáà ran àwọn tí wọn wá ènìyàn wọn lọwọ

A gbọ́ pé kí wọn tó bẹ̀rẹ̀ ìkọlù, ẹbí náà de adó olóró mọ́'ra wọ́n sì pín ara wọn sí ọ̀nà méji. Ìyá àti ọmọbinrin wọn méjì ṣe ìkọlù sí ilé ìjọ́sìn kan, bí bàbá àti ọmọkùnrin méjì náà sì ṣe ìkọlù sí ilé ìjọsin méjì.

Àwọn ọmọbinrin náà jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́sàn àti méjìla tí àwọn ọmọkùnrin sì jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́rìnlélógún àti méjìdínlógún.

Ìwádii fi hàn pé ìdílé náà gbé fún ìgbá ráńpẹ́ ní Syria.

Ìkọlù míràn ní ọjọ́ ajé

Ni ọjọ́ ajé, ìkọlù mìíran tún ṣẹlẹ̀ ní orilẹ̀èdè Indonesia ni olú ilé iṣẹ́ àwọn ọlọ́páà tí ó wà ní Surabaya.

Àwọn aláṣẹ ní ọ̀kadà ni awọn agbésùmọ̀mí náà fi ṣe ìkọlù náà.