Tunde Kelani: Èmi ò jẹ́ Baba Wande lówó lórí fíìmù Ti Olúwa nilẹ̀

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionTunde Kelani; Èmi ò jẹ́ Baba Wande ní owó lórí fíímù Tolúwanilẹ̀

Gbajugbaja olosere Tunde Kelani ti sọ wi pe irọ ni ọrọ ti Baba Wande sọ, wi pe o yan oun jẹ, lori owo to san fun un lorii fiimu ‘Ti Olúwa nilẹ̀’.

Fun igba diẹ bayii ni ariyanjiyan ti wa lori ẹni to ni fiimu ‘Ti Olúwa nilẹ̀’ ti ‘Mainframe’ gbe jade lọdun 1993, pẹlu Kareem Adepoju ti gbogbo eniyan mo si ‘Baba Wande’, ti Tunde Kelani si se olootu rẹ.

Tunde Kelani nigba to n ba BBC sọrọ sọ wi pe oun ko yan Baba Wande jẹ, ati wi pe ẹtọ rẹ lohun fun un lẹyin ti won gbe fiimu naa jade, lẹyin to sọ wi pe awọn to n se ayederu filmu naa ko jẹ ki ere ko wa lori rẹ.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media caption‘Tunde Kelani yan mi jẹ lori fiimu ‘Toluwanilẹ’

Lopin ọsẹ ni Iwe Iroyin kan sọ pé Baba Wande fẹsun kan Tunde Kelani wi pe owo to tọ si oun, kọ ni wọn fun oun lori fillmu naa ti o si jẹ wipe oun lo kọ itan naa.

Amọ, Baba Wande nigba to n ba BBC sọrọ wi pe oun ko ni ija pẹlu Tunde Kelani, sugbọn otitọ ni wi pe Kelani yan oun jẹ lori filmu naa.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionỌ̀nà ọ̀fun lọ̀nà ọ̀run - omi ò jẹ́ ká ta ọjà