Tanzania: Ọ̀rànyàn kọ́ láti ní iléesẹ́ asojú sí Jerusalem

Àsìá Orílẹ̀èdè Tanzania Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Tanzania kò ní sí ilé isẹ́ sí Jerusalem

Mínísítà fún ọ̀rọ̀ ilẹ̀ òkèrè lórílẹ̀èdè Tanzania, ọ̀mọ̀wé Augustine Mahiga sọ wípé orílẹ̀èdè Tanzania kò le è sí ilé isẹ́ tirẹ̀ ṣí ile iṣẹ́ tirẹ̀ sí Jerusalem.

Ó ní ṣíṣe èyí yóò tako àfẹnukò ìgbìmọ̀ tó ń rí sí àbò ní àjọ ìsọ̀kan àgbáyé, UN èyí tó rí Jerusalem gẹ́gẹ́ bí ìlú tí onírúurú ọ̀rọ̀ ti pọ̀ lórí ẹ̀ tẹ́lẹ̀.

Ọ̀gbẹ́ni Mahiga sọ èyí ní Dar es Salaam níbi ìpàde kan tí ó pè sáájú lónìí láti bá àwọn oníròyìn sọ̀rọ̀ lórí ìrìnàjò rẹ̀ lọ sí Isreal níbi tó ti pàde olóòtú Benjamin Netanyahu níbi tí wọ́n ti jíròrò nípa orísirísi ọ̀rọ̀ tó fi mọ́ síse pàsípàrọ́ ohun èlò ẹ̀rọ̀ ti iṣẹ́ àgbẹ̀.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ìgbésẹ̀ Tanzania yìí wáyé lẹ́yìn wákàtí díẹ̀ tí orílẹ̀èdè Amẹ́ríkà gbé ìgbésẹ̀ láti gbé ilé iṣẹ́ wọn tó wà ní Tel Aviv lọ sí Jerusalem.

A kò leè lọ sí Jerusalem, àfi bí àjọ UN bá fọwọ́ síi

Mahiga tún sọ wí pé, " A ti bá ṣí ilé isẹ́ sí ilẹ̀ Isreal tẹ́lẹ̀, kò pọn dandan inú ìlú tó wà, ó kàn túmọ̀ sí wí pé, a ti padà sórí ilẹ̀ Isreal ni. Sùgbọn lẹ́ẹ̀kejì, àwọn náà mọ̀ pe, gbígbé ilé isẹ́ wa kúrò ní Isreal tako àfẹnukò àjọ UN wí pé, ìlú tí ẹjọ́ pọ̀ lórí ẹ̀ ni Jerusalem jẹ́, àyàfi bí gbọ́nmi sí i omi ò tó o tó wà láàrin ilẹ̀ Isreal àti Palestine ba parí, ìgbà yẹn ni a tó lè ronú lílọ síbẹ̀".

Ó ní "gbogbo ìlú ló fẹ́rẹ̀ẹ́ ní ilé iṣẹ́ ní Tel Aviv, a ò sì lè lọ sí Jerusalem, àfi bí àjọ UN bá fọwọ́ sí i"