Ajímọ̀bí: Ẹ tẹ́wọ́gba ipò tuntun yín láti sin aráàlú

Gomina Ajimọbi n n ki ọkan lara awọn alaga kansu tuntun ku oriire Image copyright Facebook/aaajimobi
Àkọlé àwòrán Eyi ni igba akọkọ laarin ọdun mẹjọ ti agbekalẹ ijọba ibilẹ yoo maa waye nipinlẹ Ọyọ

Wọn ti bura wọle fun awọn alaga kansu tuntun ti wọn ṣẹṣẹ dibo yan nipinlẹ Ọyọ.

Adajọ agba nipinlẹ Ọyọ, Onidajọ Muntar Abimbola lo seto ijẹjẹ fawọn alaga kansu tuntun naa ni gbọngan awọn lọbalọba to wa nile ijọba ipinlẹ Ọyọ to wa l'Agodi nilu Ibadan.

Image copyright Facebook/aaajimobi
Àkọlé àwòrán Ẹgbẹ́ òṣèlú APC ló borí gbogbo ìjòkó alága káńsù àti káńsílọ̀ níbi ìdìbò ìjọba ìbílẹ̀ nípínlẹ̀ Ọ̀yọ́

Ninu ọrọ rẹ, gomina ipinlẹ Ọyọ, Sẹnetọ Abiọla Ajimọbi ni awọn alaga kansu naa gbọdọ ri ipo tuntun wọn naa gẹgẹ bii ipe si iṣiṣẹ sin ilu ati awọn eeyan to yan wọn sipo.

"Ẹ bojuwo idibo yan sipo yin gẹgẹ bii ipe si si iṣiṣẹ sin ilu. Eto idari yin gbọdọ ṣe afihan ilana to fi araalu ṣe ọpakutẹlẹ eto rẹ gbogbo ni ibamu pẹlu awọn amuyẹ iṣejọba wa."

Image copyright Facebook/Aaajimobi
Àkọlé àwòrán Aṣalẹ ọjọ aiku ni ajọ eleto idibo ipinlẹ Ọyọ, OYSIEC, kede esi idibo naa

Ni ọjọ abamẹta ni eto idibo si ipo alaga kansu waye ni ipinlẹ Ọyọ esi eyi to fihan pe awọn oludije ẹgbẹ oṣelu APC lo bori ni gbogbo ijọba ibilẹ mẹtalelọgbọn, agbegbe idagbasoke, LCDA marunlelọgbọn ati ẹgbẹta o le mẹwa wọọdu idibo to wa nibẹ.

Aṣalẹ ọjọ aiku ni alaga ajọ eleto idibo ipinlẹ Ọyọ, OYSIEC, Jide Ajeigbe kede esi idibo naa eleyi to ṣe atọna fun ibura wọle fun awọn alaga ati kansilọ tuntun naa.

Eyi ni igba akọkọ laarin nkan bii ọdun mẹjọ ti agbekalẹ ijọba ibilẹ yoo maa waye nipinlẹ Ọyọ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí: