Ẹgbẹ́ ajàfẹ́tọ́: Ọ̀pọ̀ ilé ọlá ni darandaran sọ d’ahoro

Ẹgbẹ ajafẹtọ ọmọniyan to n pe ipe naa Image copyright @Areafada1
Àkọlé àwòrán Àwọn ajàfẹ́tọ́ náà ní kò dín ní ẹgbẹ̀rún ẹ̀mí tí àwọn darandaran ti pa lọ́dún 2018 nìkan

Ẹgbẹ ajafẹtọ ọmọniyan kan lorilẹede Naijiria ti ke gbajare lọ ba ileeṣẹ eto idajọ lábẹ́ ijọba apapọ pe, asiko to fun Aarẹ Muhammadu Buhari lati lẹ orukọ agbesunmọmi mọ awọn daradaran Fulani to n gbẹmi awọn eeyan kaakiri bayii lara.

Charly boy, gbajugbaja adani-laraya ni, lo lewaju awọn ẹgbẹ ajafẹtọ ọmọniyan naa.

Awọn ajafẹtọ aralu ọhun ni, ọgọọrọ ẹmi lawọn apanilẹkun-jaye darandaran naa ti ṣekupa, ti wọn si ti sọ ọpọ ile ọla ati ilu di ahoro.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Gẹgẹbii akọsilẹ ajọ kan, 'Global Terrorism' to n tọpinpin iwa igbesunmọmi lagbaye, ,ẹgbẹrun meji ati ẹẹdẹgbẹta eeyan lawọn darandaran apani-jaye ti pa laarin ọdun 2012 si 2016 lorilẹede Naijiria.

Ni oṣu kẹta ọdun yii, ko din ni eeyan mẹrindinlọgbọn ti wọn pa ni ileto kan nipinlẹ Benue.

Loṣu to kọja, eeyan mejidinlogun ninu eyi ti ati ri oluṣọ-aguntan ijọ aguda meji ni wọn pa ni ipinlẹ Benue kan naa.

Eyi kii se igba akọkọ ti ẹgbẹ yoowu yoo ma dide naro si ijọba, lati kede awọn darandaran gẹgẹ bii agbesunmọnmi.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ọ̀pọ̀ èèyàn ló ti ń késí ìjọba Nàíjíríà láti wá ojútùú sí ìkọlù darandaran

Ẹgbẹ ajafẹtọ marun-un lo kora jọ labẹ ẹgbẹ naa, ti wọn si kede pe, ko din ni ẹgbẹrun kan eeyan ti awọn darandaran Fulani aṣeku-pani ti pa lọdun yii nikan.

Ijọba ko tii fesi si ipe yii

Bakanaa, ni wọn tun sọọ di mimọ, lasiko iwọde wọn naa pe, ọrọ ti aarẹ sọ lorilẹede Amẹrika ati Gẹẹsi pe, awọn agbebọn lati orilẹede Libya lo ya wọ Naijiria lati maa pa awọn eeyan bi ẹni pa ẹran, ko jẹ itẹwọgba.

Ni bayii naa, ijọba ko tii fesi si ipe yii.