Gaza: Palestine yóò sìnkú ènìyàn méjìdínlọ́gọ́ta lẹ́ẹ̀ẹkan soso

Àwọn ará Palestine Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Àwọn ará Palestine pàdánù ènìyàn méjìdínlọ́gọ́ta

Òní ló búrú jù nínú ìṣẹ̀lẹ̀ ìpànìyàn tó ti ń wáyé ní ilẹ̀ Palestine gẹ́gẹ́ bí wọ́n se pàdánù ènìyàn méjìdínlọ́gọ́ta látàri ìfilọ́lẹ̀ ilé isẹ́ orílẹ̀èdè Amẹ́ríkà ní Jerusalemu.

Ètò ìsínkú yóò wáyé fún ènìyàn méjìdínlọ́gọ́ta tí wọ́n pa lọ́jọ́ ajé ní ìlú Gaza nígbà tí ikọ̀ ọmọ ogun ilẹ̀ Ísrẹ́lì da iná bolẹ̀ tí wọ́n kojú àwọn afẹ̀hónú hàn Palestine lọ́jọ́ tó burú jáì látigbà ogun kan lọ́dún 2014.

Àwọn ọmọ ogun ilẹ̀ Ísrẹ́lì ní àwọn ń múra ogun sùgbọ́n ikọ̀ ti Palestine jẹ́ kó di mímọ̀ pé àwọn ni yóò borí nì Ọjọ́ Ìṣẹ́gun.

Ètò ìsínkú náà se kòńgẹ́ ohun tí àwọn ará Palestine ń pè ní Nakba ìyẹn, ayẹyẹ àádọ́rin ọdún tí wọ́n ṣí àwọn ará Palestine nípò kúrò nílùú wọn lẹ̀yìn ìdásílẹ̀ Isrẹ́li.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Àwọn ikọ̀ Palestine jẹ́ kó di mímọ̀ pé àwọn ni yóò borí lọ́jọ́ ìṣẹ́gun.

Ìṣẹ̀lẹ̀ ọjọ́ ajé wáyé látàrí bí orílẹ̀èdè Amẹ́ríkà se se ìfilọ́ọ́lẹ̀ ilé iṣẹ́ àkọ́kọ́ rẹ̀ ní Jerusalẹmu, èyí tó jẹ́ ìgbésẹ̀ tó tako ìlànà orílẹ̀èdè naa àti Palestine tí wọ́n ńkóna ogun mọ́ báyìí

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí: