Òpópónà Eko si Abeokuta yóò ní àyípadà láìpẹ́

Òpópónà Eko si Abeokuta Image copyright @FOLLOWLASTMA
Àkọlé àwòrán Òpópónà Eko si Abeokuta ti ń fíyà jẹ àwọn ará ilú láti ọjọ́ tó ti pẹ́

Iṣẹ́ ti bẹ̀rẹ̀ ní pẹrẹwu lorí àtúnṣe òpópónà Eko sí Abeokuta ti Minisita fun Ọ̀rọ̀ Ise, Ina ati Ilé ìgbé Babatunde Fasola ni ìjọba àpapọ̀ yóò ná bilionu méjìlélógun naira àti díẹ̀ sí.

Ọ̀nà náà ti ń fíyà jẹ àwọn ará ilú tí ó ń gbé agbègbè òpópónà yìí láti ọjọ́ tó ti pẹ́ látàri bi àgbàrá omi ṣe máa ń bo ọ̀nà náà nígbàkúgbà tí òjò bá rọ̀.

A gbọ̀ pé wọ́n ti ń kó àwọn irin iṣẹ́ dé ibẹ bayìí bí alákoso iṣẹ́ ọ̀nà, Olalekan Busari ṣe lọ ṣe abẹ̀wò sí ibẹi iṣẹ́ náà ní ọjọ́ aje.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionỌ̀nà ọ̀fun lọ̀nà ọ̀run - omi ò jẹ́ ká ta ọjà

Busari ní ọ̀na náà jẹ́ ọgọ́rin kìlómítà, ogún ninu rẹ̀ wa nínú Ipinlẹ̀ Ekó bí Ọgọ́ta ninu rẹ̀ ṣe wà nínú Ipinlẹ̀ Ogun.

Ọjọ́ kẹrìnlá oṣù yìí ni ìjọba àpapọ̀ bu wọ́ lu ìwé àdéhùn láti tún ọ̀nà náà ṣe, èyí tí yóò gba ọdún méjì àti ààbọ̀. Ile Zic ni iṣẹ́ yóó ti bẹ̀rẹ̀.