Kí ló ń ṣẹlẹ̀ nípa ìwádìí ìfipá bani lo pọ̀ ibùdó IDP?

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Iwádìí f'ẹ̀sùn kan àwọn òṣìṣẹ́ àjọ NEMA pé wọ́n fipá bá àwọn ti o n gbé ibùdó àwón tí ogún lé kúrò nílé lò

Ọdún mejì lẹ́yìn tí àjọ tí ó n kojú ìṣẹ̀lẹ̀ pajáwirì (NEMA) ṣe ìpinnu pé wọn yóò ṣe ìwádìí lórí ẹ̀sùn pé àwọn òṣìṣẹ́ àjọ náà n fipá bá àwọn ti o n gbé ibùdó àwón tí ogún lé kúrò nílé lò ki wọn tó fún wọn l'òuǹjẹ, a kò tíì gbọ ǹkankan lórì ọ̀rọ̀ náà.

BBC kàn sí ọga àjọ tó ń kojú ìsẹ̀lẹ̀ pàjáwìrì ti ìpínlẹ̀ Borno (SEMA ), Hajia Ya Bawa Kolo láti gbọ́ lẹ́nu rẹ̀, ṣùgbọ́n ó ní òun kò mọ ǹkankan nípa ọ̀rọ̀ náà o, nítorí òun ṣẹ̀ṣẹ̀ gba iṣẹ́ ni.

Kolo ni, "Ṣé ẹ mọ̀ pé tí eènìyàn kò bá mọ̀ nipa ǹkan dáadán kò dára kí ènìyan máa bá àwọn oníròyìn sọ̀rọ̀ lórí rẹ̀. Mò ṣẹ̀ṣẹ̀ ń ṣe àtúntò àjọ náà ni báyìí. Lọ́wọ́lọ́wọ́, ọ̀rọ̀ oúnjẹ fún àwọn tí ó ń gbé ibùdó nígbà Ramadan ni ó jẹ mí lógún. Tí mo bá ti mọ ǹkankan nípa ọ̀rọ̀ náà máà jẹ́ kẹ́ẹ gbọ́."

Ọ̀rọ̀ náà jẹ yọ nígbà tí fídíò kan jáde lórí Twitter nínú èyí tí Kọmíṣọ́nà fún Ọ̀rọ̀ Obìnrin ni Ipinlẹ̀ Borno nigbà kan rí, Hajiya Maryam Bukar Petrol sọ bí wọn ṣe ń fipa bá àwọn obinrin lò lórí ounjẹ.

A kò mọ ìgbà áti ibi tí wọ́n ti ya fídíò náà.