Ìjínigbé Kaduna: Àwọn agbébọn jí ènìyàn tó lé ní ọgọ́rin

Ọkọ̀ àwọn ọmọ ogun Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ọ̀gá àwọn ọ̀mọ̀ ogun Nàìjíríà ti sèbẹ̀wò síbi ìsẹ̀lẹ̀ náà

Ò lé ní ọgọ́rin ènìyàn tí àwọn agbébọn jí gbé ní ìpínlẹ̀ Kaduna, tó wà ní apá ìwọ̀ oòrùn àríwá orílẹ̀èdè Nàìjíríà.

Àwọn òṣìṣẹ́ tó n bojù tó ìrìn ojú pópó sọ wí pé, wọ́n jí àwọn ènìyàn náà bí wọ́n sé ń rìnrìn àjò ní òpópónà márosẹ̀ kan tó so ìhà àríwá mọ́ Gúúsù.

Ó ti pẹ́ tí irú ìṣẹ̀lẹ̀ ìjínigbé láti gba owó ní apá ìwọ̀ oòrùn ti máa ń sẹlẹ̀, sùgbọ́n irú èyí tó sẹ̀lẹ̀ ní Kaduna lọ́tẹ̀ yìí kò sẹlẹ̀ rí.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àwọn olùgbé àti òsìsẹ́ tó ń bojù tó ìrìn ojú pópó ní ìlú Birnin-Gwari sọ wí pé, ní ọjọ́ náà, àwọn agbébọn dá ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọkọ̀ dúró, wọ́n rọ́ ènìyàn púpọ̀ lọ sínú igbó, wọ́n sì pa àwọn ọkọ̀ tì síbẹ̀.

Image copyright AFP
Àkọlé àwòrán Wọ́n jí àwọn arìnrìnàjò gbe ní òpópónà márosẹ̀

Àwọn agbébọn pa ènìyàn tó lé ní àádọ́ta lọ́sẹ̀ tó kọjá

Sùgbọ́n àwọ̀n ọlọ́pàá kò tíì fèsì lórí ọ̀rọ̀ ìsẹ̀lẹ̀ náà.

Ìròyìn kan sọ wí pé, àwọn ajínigbé náà ti bẹ̀rẹ̀ sí ní kàn sí àwọn ẹbí fún owó. Lọ́jọ́ ajé, ọ̀gá àwọn ọ̀mọ̀ ogun Nàìjíríà sèbẹ̀wò síbẹ̀ láti fi kún ìgbésẹ̀ àbò.

Àwọn agbébọn pa ènìyàn tó lé ní àádọ́ta ní abúle kan lágbègbè kan náà lọ́sẹ̀ tó kọjá.