Jlloyd Samuel: Wigan àti West Brom ṣè'rántí olóògbe

Jlloyd Tafari Samuel Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ìgba mọ̀kàndínlọ́gọ́rùń ni Samuel gbá bọ́ọ̀lù fún Villa lẹ́yìn ìgba tí ó dé bẹ̀ ní 1998

Oríṣiríṣi ọ̀rọ̀ ìwúrí ni ó ti n wọlé láti ranti ìgbà ayé agbọ́bọ́ọ̀lu Aston Villa ati Bolton nígbà kan rí, Jlloyd Samuel, tí ó gbẹ́mìí mì lẹ́yìn ìṣẹ̀lẹ̀ ìjàǹbá ọkọ̀ ní ọjọ́ Ìṣẹ́gun ní Cheshire.

Awọn akẹgbẹ́ Samuel tí ó ṣe alákóso fun Egerton, pàtẹ́wọ́ fun ìṣẹ́jú kan làti buyì kún olóògbé náà ní pápá ìṣeré Villa Park kí ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ Villa àti Middlesbrough tó bẹ̀rẹ̀ ní ọjọ́ Ìṣẹ́gun.

Àwọn tí ó wá wo ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ náà kò gbẹ́yìn, ṣe ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí ní kọrin yin Samuel.

Image copyright Reuters
Àkọlé àwòrán Awọn akẹgbẹ́ Samuel pàtẹ́wọ́ fun ìṣẹ́jú kan làti buyì kún olóògbé náà ni Villa Park

Nínú ọ̀rọ̀ rọ̀, agbábọ́ọ̀lu Wigan àti West Brom nígbà kan rí, Nathan Ellington, tí òun àti Samuel jọ wà ní Egerton ní ọ̀rọ̀ náà dun òun gan ni nítórí ènìyàn dáradára ni olóògbé náà.

Ìgba mọ̀kàndínlọ́gọ́rùń ni Samuel gbá bọ́ọ̀lù fún Villa lẹ́yìn ìgba tí ó dé 'bẹ̀ ní ọdún 1998. Lẹ́yìn tó dé Bolton, ó gbá bọ́ọ̀lu lẹ́ẹ̀mẹ́tàlelọ́gọ́rin laarin ọdún 2007 sí 2011. Ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lu kan ní orilẹ̀ede Iran ni ó ti gbá bọ́ọ̀lu kẹ́hìn.

Related Topics