Ọmọge Campus fayé sílẹ̀ ní Canada

Aisha Abimbọla
Àkọlé àwòrán Oniruuru ere ori itage ni Aisha Abimbọla ti se sita

Gbájú-gbajà òsèré tíátà obìnrin, Aisha Abimbọla, tí ọ̀pọ̀ èèyàn mọ̀ sí ‘Ọmọge Campus’ tí jáde láyé ní orílẹ̀èdè Canada.

Aisha ni ìròyìn gbalẹ̀ kan ní ààrọ̀ ọjọ́rú lórí ìtàkùn àgbáyé pé ó ti mí kanlẹ̀ lásìkò àìsàn ọlọ́jọ́ gbọọrọ.

A gbọ́ pé àìsàn jẹjẹrẹ ọyàn tó ń bá Aisha fínra láti ọjọ́ díẹ̀ ló gba ẹ̀mi rẹ̀.

Ọ̀pọ̀ àwọn òsèré tíátà, tí wọn jẹ́ akẹẹgbẹ́ rẹ̀ ni wọ́n ń se ìdárò ikú ìlúmọ̀ọ́ká òsèrè tíátá obìnrin náà láwọn ojú òpó ìkànsíra ẹni wọn lórí ìtàkùn àgbáyé Facebook àti Instagram.

Lásìkò tó ń fi ìdí ìsẹ̀lẹ̀ yìí múlẹ̀ fún BBC Yorùbá, àgbà òsèré tíátá ni, Adebayọ Salami, tí gbogbo èèyàn mọ̀ sí Ọ̀gá Bello sàlàyé pé lóótọ̀ ni wọ́n pe òun ní ààrọ̀ ọjọ́rú pé ìlúmọ̀ọ́ká òsèrè tíátá obìnrin náà ti tẹ́rí gba asọ̀.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionỌ̀gá Bello: Ikú Aisha Abimbọla ká wa lára

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ọ̀pọ̀ àwọn ọmọ Nàíjíríà ló ti ń se ìdárò ikú àgbà òsèré tó dará ilẹ̀ náà ní ojú òpó Twitter wọn.

Àkọlé àwòrán Lara tiata ti Aisha se ni Omoge Campus