Ìsúná 2018: N9trn ni àwọn aṣòfin fòǹtẹ̀ lù

Ọpa asẹ ile asofin agba ati ami idamọ wọn Image copyright @NGRSenate
Àkọlé àwòrán Ile aṣofin mejeeji gbe aba naa lọ si triliọnu mẹsan o le diẹ.

Ile igbimo Aṣofin agba orilẹede Naijiria l'Abuja ti f'ọwọ si abadofin eto isuna fun ọdun 2018 .

Abadofin naa le ni triliọnu mẹsan naira.

Ile Aṣofin agba l'Abuja buwọ lu abadofin naa, lẹyin ti ile ṣ'ayẹwo abọ igbimọ ile aṣofin mejeeji lori eto isuna.

Aarẹ Muhammadu Buhari ti kọkọ gbe abadofin bi triliọnu mẹjọ abọ lọ siwaju ile tẹlẹ ni oṣu kọkanla ọdun 2017.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ṣugbọn ile aṣofin mejeeji gbe aba naa lọ si triliọnu mẹsan o le diẹ.

Ile yoo da isuna naa pada s'ọdọ aarẹ Buhari lati bu ọwọ lu.

Ni ọjọ aje ni Sẹnetọ Danjuma Goje, to jẹ alaga igbimọ naa, gbe ayẹwo iṣuna naa si iwaju ile.

Image copyright @bukolasaraki
Àkọlé àwòrán Tírílíọ̀nù mẹ́sán náírà ni àwọn aṣòfin buwọ́lù

Ni ọjọ kẹrinlelogun oṣu kẹrin ni awọn aṣofin agba kọkọ ti pinnu lati buwọlu aba naa, ṣugbọn to kuna lati ṣe bẹ́ẹ̀.

Ọpọ awuyewuye lo ti waye lori bi bibuwọlu aba iṣuna ṣe n falẹ niwaju igbimọ aṣofin apapọ, lati ọdun to kọja ti Aarẹ Buhari ti gbe e kalẹ niwaju ijoko apapọ awọn aṣofin agba ati awọn aṣoju-ṣofin orilẹede Naijiria.

Ile mejeeji fẹnuko si tiriliọnu mẹsan o le díẹ̀

Awọn aṣoju-ṣofin ni tiwọn ti kede pe, ọjọọru ni awọn yoo buwọlu abadofin eto iṣuna oni tiriliọnu mẹsan-an o le diẹ naa. Aba eto iṣuna ti ile aṣofin agba ati aṣoju-ṣofin panupọ le lori, fi irinwo o le mẹwa biliọnu naira ga ju eyi ti aarẹ gbe ka iwaju awọn aṣofin apapọ.

Tiriliọnu mẹjọ ati ẹgbẹta biliọnu, N8.61 trilion, ni aba iṣuna ti aarẹ ṣeto siwaju awọn aṣofin apapọ, ṣugbọn lẹyin ijiroro, gbogbo ẹka ile mejeeji fẹnuko si tiriliọnu mẹsan o le ọgọfa biliọnu naira, N9.12 trilion.