Ọlọ́pàá Èkó: Ẹ̀wọ̀n ọdun márùn-un fún ilé-wòsàn tó kọ ọgbẹ́ ọta ìbọn

Ẹsẹ ẹni to ba ni ọgbẹ ibọn Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Dandan ni fun gbogbo ile iwosan lati fun ẹnikẹni ti o ba ni ọgbẹ ibọn lara n'itọju,

Kọmisọna ọlọpaa Ipinlẹ Eko Imohimi Edgal ti sọ pe, awọn agbofinro yoo bẹre si maa mu gbogbo ile iwosan ti wọn ba kọ lati tọju awọn to fara gb'ọta.

Ọga ọlọpaa naa sọ pe, ẹwọn ọdun marun un ni ẹnikẹni t'ọwọ ba tẹ yoo fara gba labẹ ofin.

O fi kun ọrọ rẹ pe, o pọn dandan fun gbogbo ile iwosan lati fun ẹnikẹni ti o ba ni ọgbẹ ibọn lara n'itọju, koda ti ko ba ni aṣẹ ọlọpaa.

Ọrọ naa jẹyọ leyin igbati wọn ka ninu iwe iroyin, bi ile iwosan kan ṣe kọ lati tọju ọkunrin kan pẹlu ọgbẹ ọta ibọn lara rẹ.

Image copyright Twitter/Imohimi Edgal
Àkọlé àwòrán ẹ̀wọ̀n ọdún márùn ún ni ìjìyà fún ilé ìwòsàn tí kò bá tójú afagbọta''

Ọkunrin naa, to jẹ amoju-ẹrọ, Adebayo Akinwunmi ni, awọn adigunjale yinbọn fun oun ninu ile oun, toun si farapa yanna-yanna ni agbegbe Ofada-Mokoloki, ni Ipinlẹ Ogun.

Ṣugbọn ile iwosan ti wọn gbe lọ ni Ikeja kọ lati tọju rẹ, lẹyin igbati wọn sọ pe wọn o gbaṣẹ lati ọdọ awọn ọlọpaa.