Fáyẹmí kàn sí Buhari lẹ́yìn tó borí l'Ékìtì

Ọmọwe kayọde Fayẹmi, Aarẹ Buhari ati Gomina Al-Makura Tanko ti ipinlẹ Nasarawa Image copyright Nigeria Presidency
Àkọlé àwòrán Fáyẹmí ló borí ìbò abẹ́nú ẹgbẹ́ òṣèlú APC nípínlẹ̀ Èkìtì

Aarẹ Buhari ti gba oludije fun ipo gomina ni ipinlẹ Ekiti labẹ aṣia ẹgbẹ oṣelu APC lalejo, nile ijọba to wa ni Aso rock nilu Abuja.

Fayẹmi kan si aarẹ lẹyin to jawe olubori nibi idije 'tani yoo ṣoju ẹgbẹ oṣelu APC' nibi idibo fun ipo gomina ipinlẹ Ekiti, ti yoo waye loṣu keje ọdun 2018.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Gomina Al-Makura Tanko ti ipinlẹ Nasarawa, to ṣe aayan idibo abẹnu naa kọwọrin pẹlu Ọmọwe Fayẹmi lọ ṣabẹwo si aarẹ Buhari.

Ni ọjọ abamẹta to kọja ni minisita fọrọ iwakusa ati ohun alumọni ilẹ, Ọmọwe kayọde Fayẹmi, gba aṣia ẹgbẹ oṣelu APC lati dije lorukọ ẹgbẹ oṣelu naa, lasiko eto idibo sipo gomina nipinlẹ Ekiti ti yoo waye ni ọjọ kẹrinla oṣu keje ọdun 2018.