Ìbarùn-ún Eko: Aya Ambode yoo san N500,000 losoosu

Aworan awon ibaarun kan Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Gomina Ambode gan ko gbẹyin ni idi itọju awọn ọmọ tuntun jojolo naa,

Iyawo Gomina ipinle Eko, Bọlanle Ambode ti jẹjẹ pe, oun yoo maa san ẹẹdẹgbẹta naira losoosu fun osu mejila, fún àwọn ìbarùn-ún tí obìnrin kan bí ní ìlú Èkó.

Iyawo gomina jẹjẹ ohun, lasiko to sabẹwo si idile Ogbeni Augustine Obiefuna, ti iyawo rẹ bi ọmọ marun-un lẹẹkan ṣoṣo, lagbegbe Orile- Iganmu ni ipinle Eko.

Bakan naa lo tun jẹjẹ pe, oun yoo maa pese iledi igbalode (pampers), Miliki, ati gbogbo awon nkan tawọn ọmọ naa yoo nilo laaarin odun kan.

Image copyright @lagos state govt
Àkọlé àwòrán Bọlanle Ambode rọ awọn obinrin ni ìpinle Eko láti máa lọ sí ilé ìwòsàn tó pójú owó nínú oyún.

Abileko Ambode gbe apoti Aṣọ meji, Beedi, ibọsẹ àti fila gẹgẹ bii ẹbun fun awọn ẹbun Ọlọrun naa.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionỌ̀nà àbáyọ sí àìrọ́mọbí tọkùnrin tobìnrin

Kò tan sibẹ, Gomina Ambode gan ko gbẹyin ni idi itọju awọn ọmọ tuntun jojolo naa, to si jeje owo, ti ko sọ iye rẹ pato, fun itoju awon ọmọ ọkunrin mẹta ati obinrin meji ọhun.

Aya Gomina Ambode bakan naa, tun ro awọn obinrin ni pinile Eko, lati maa lọ si ile iwosan to poju owo ninu oyun, ki wọn si dẹkun oogun lilo lọwọ ara wọn.

O wa gboriyin fawọn akọṣẹmọṣẹ Onisegun to gbẹbi awon ọmọ naa nile igbẹbi Lagos Island Maternity.