Ìdílé Aisha àti ìjọba Canada ló se agbátẹrù sìnkú rẹ̀

Aisha Abimbola Image copyright Aisha Abimbola/Facebook
Àkọlé àwòrán Ọmọge Campus jáde láyé ní orílẹ̀èdè Canada ní ààrọ̀ ọjọ́rú, wọn sì sín síbẹ̀.

Aago mẹ́jọ alẹ́ ọjọ́rú ni wọn sìnkú olóògbé Aisha Abimbọla ní orílẹ̀èdè Canada.

Gẹ̀gẹ̀ bí àtẹ̀jáde láti ọwọ́ ẹgbẹ́ Golden Movie Ambassadors of Nigeria, ìsìnkú náà ti wáyé ni agogo mẹ́jọ àbọ̀ alẹ́ ti orílẹ̀èdè Naijiria.

Aisha Abimbọla, tí ọ̀pọ̀ èèyàn mọ̀ sí ‘Ọmọge Campus’ ló jáde láyé ní orílẹ̀èdè Canada ní ààrọ̀ ọjọ́rú.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Aisha ni ìròyìn gbalẹ̀ kan ní ààrọ̀ ọjọ́rú pé ó ti mí kanlẹ̀ lásìkò àìsàn ọlọ́jọ́ gbọọrọ.

Image copyright Aisha Abimbola/Instagram
Àkọlé àwòrán O digba

A gbọ́ pé àìsàn jẹjẹrẹ ọyàn tó ń bá Aisha fínra láti ọjọ́ díẹ̀, ló gba ẹ̀mi rẹ̀.

Ọ̀pọ̀ àwọn òsèré tíátà, tí wọn jẹ́ akẹẹgbẹ́ rẹ̀ ni wọ́n ń se ìdárò ikú ìlúmọ̀ọ́ká òsèrè tíátá obìnrin náà, láwọn ojú òpó ìkànsíra ẹni wọn lórí ìtàkùn àgbáyé Facebook àti Instagram.