Nollywood: Àwọn òsèré tíátà Nàìjíríà tó jẹ́ ọmọ Yorùbá

Wale Okunnu

Oríṣun àwòrán, Wale Akorede Okunnu/Facebook

Àkọlé àwòrán,

Òsèré Tíátà Wale Akorede Okunnu

Wale Akorede Okunnu

A bí i ní ìlú Ibadan ìpínlẹ̀ Ọyọ ní ọjọ́ karùn-ún osù kọkànlá ọdún 1967 sùgbọ́n ọmọ bíbi ìlú Ogbmọsọ ní ìpínlẹ̀ Ọyọ ni .

Ó jẹ́ onísòwò asọ fún bí i ọdún mẹ́tàlá kó tó di pé ó dara pọ̀ mọ́ eré Tíátà tó sì bẹ̀rẹ̀ sí pa'wó látara rẹ̀ lọ́dún 1984.

Oríṣun àwòrán, Ronke Oshodi Oke/Facebook

Àkọlé àwòrán,

Òsèré Tíátà Ronke Oshodi Oke

Ronke Ojo

Ọmọ bíbí ìpínlẹ̀ Ondo sùgbọ́n tí wọ́n bí ní agbègbè Oworonshoki ni ìpínlẹ̀ Eko ni. A bí i ní ọjọ́ kẹtàdínlógún osú keje, ọdún 1974.

Òsèré Tíátà ọmọ nàìjíríà, olórin, olùdarí àti olóòtú. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ mọ̀ ọ́ sí Ronke Oshodi Oke. Ó Bẹ̀rẹ̀ eré rẹ̀ pẹ̀lú ẹ́gbẹ́ eléré ìtàgé kan tó ń jẹ́ Star Parade lábẹ́ ìdarí Fadeyi t'òun náà jẹ́ òsèrè.

Ó bẹ̀rẹ̀ orin kíkọ ní ọdún 2014.

Oríṣun àwòrán, @odunomoadekola

Àkọlé àwòrán,

Òsèré Tíátà Odunlade Adekola

Odunlade Adekola

A bí i ní ọjọ́ kọkànlélọ́gbọ̀n osù kejìlá ọdún 1978. Ọmọ bíbí ìpínlẹ̀ Ekiti ni Odunlade. Òsèré tíátà, olóòtú àti olùdarí eré ní Nàìjíríà ni. Òhun ni alásẹ àti olùdarí ilé isẹ́ fíìmù Odunlade Adekola. Ó bẹ̀rẹ̀ eré tíátà rẹ̀ ní kékeré nípa síse ẹ̀fẹ̀ nínú àwọn ere orí ìtàge ní ìjọ rẹ̀ nígbà náà lọ́hun.

Oríṣun àwòrán, Jaye Kuti/Facebook

Àkọlé àwòrán,

Òsèré Tíátà Jaye Kuti

Jaye Kuti

A bí i ní ìlú Ilaro, ìpínlẹ̀ Ogun ní ọjọ́ kẹ́wàá osù keje. Ó gbàgbọ́ pé gbogbo ìgbà lòun ń jẹ́ ọ̀dọ̀ tóun sì ń rẹwà sí i.

Òsèré Tíátà, onísòwò àti olóòtú eré ni. Òun ni alákòso àti adarí ilé isẹ́ fíìmù Jaylex Aesthetic Production.

Oríṣun àwòrán, Muyiwa Ademola/Facebook

Àkọlé àwòrán,

Òsèré Tíátà Muyiwa Ademola

Muyiwa Ademola

A bí i ní ọjọ́ kẹrìndínlọ́gbọ̀n osù kínní ọdún 1971 ní Abẹokuta ìpínlẹ̀ Ogun. Òsèré Tíátà ọmọ Nàìjíríà, olóòtú àti olùdarí eré.

Ò dara pọ̀ mọ́ àwọn eléré Tíátà Nàìjíríà nípasẹ̀ Charles Olumọ tí gbogbo ènìyàn mọ̀ sí Agbako ẹni tó ń gbé ní ìlú rẹ̀ nígbà náà. Ó bẹ̀rẹ̀ síse eré gan ní ọdún 1991 ó sì gbé fíìmù àkọ́kọ́ rẹ̀ tó fọwọ́ kọ ní ọdún 1991.

Oríṣun àwòrán, Toyin Abraham/Facebook

Àkọlé àwòrán,

Òsèré Tíátà Toyin Abraham

Toyin Abraham

Ọmọ bíbí ìlú Auchi, ìlú kan ní ìpínlẹ̀ Edo ni. A bí i ní ọjọ́ karùn-ún osù kẹsan ọdún 1984 sùgbọn ìlú Ibadanní ìpínlẹ̀ Ọyọ ló gbé dàgbà.

Ó bẹ̀rẹ̀ eré síse ní ọdún 2003 nígba tí òsèré Tíátà Bukky Wright lọ se fíìmù kan ní ìlu Ibadan.

Láìpẹ́ yìí ló sẹ̀sẹ̀ gba òrùka 'sé oó fẹ mi' gẹ́gẹ́ bí ó ṣe sọ pé "mó gbọ́, mo gbà" sì ìbéèrè olólùfẹ́ rẹ tuntun láti di aya rẹ̀.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àkọlé fídíò,

Wùnmí Toríọlá: Toyin Abraham kìí se ọ̀gá mi nínú tíátà

Àkọlé fídíò,

Ope Aiyeọla: Nkan pa emi ati Baba Suwe pọ