Commonwealth: Ìdùnú ni pé orílẹ̀-èdè Zimbabwe fẹ́ padà wá

Emmerson Mnangagwa
Àkọlé àwòrán,

Aarẹ ilẹ Zimbabwe, Emmerson Mnangagwa, ni ìpinnu èrò tuntun fún Zimbabwe pẹ̀lú àwọn orílẹ̀-èdè agbaye.

Orilẹ-ede Zimbabwe ti kọ iwe lati darapọ mọ Ajọ Commonwealth, lẹyin ọdun mẹẹdogun ti wọn kuro ninu ajọ naa.

Akọwe gbogboogbo fun Ajọ Commonwealth, Patricia Scotland, ṣalaye pe inu oun dun lati gba lẹta ayọ̀ naa lati ọwọ Aarẹ orilẹ-ede Zimbabwe, ti wọn fi ransẹ ni Ọjọ Kẹẹdogun, Osu Karun, ọdun 2018.

Amọ, arabinrin Scotland naa fikun pe awọn yoo gba wọn pada si ajọ naa lẹyin ti wọn ba ti tẹle ofin tó de didarapọ mọ ajọ naa.

Aarẹ ilẹ naa, Mnangagwa to bọ sori aleefa ni Osu kọkanla, ọdun to kọja lẹyin ti wọn le aarẹ tẹlẹri, Robert Mugabe, kuro lori oye, sọ wi pe erongba oun ni lati ri i pe ifọwọsowọpọ wa laarin orilẹ-ede Zimbabwe ati ilẹ okeere.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ti a ko ba gbagbe, orilẹ-ede Zimbabwe ti wọn darapọ mọ ajọ Commonwealth to ni orilẹ-ede Mẹtalelaadọta ni ọdun 1980, yọ ara rẹ kuro ninu ajọ naa ni ọdun 2003, lẹyin ti wọn fẹsun kan wọn wi pe wọn se eto idibo ti o kún fún idarudapọ ati ibo yiyi ninu.