Benue: Látàrí ìkọlù Benue, Ìjọ Àgùdà káàkiri Nàìjíríà se ìwọ́de

Ìsìnkú ní ìpínlẹ̀ Benue, ìwọ́de ìjọ Àgùdà
Àkọlé àwòrán Látàrí ìkọlù Benue, Ìjọ Àgùdà káàkiri Nàìjíríà se ìwọ́de

Ètò ìsìnkú ti ń lọ lọ́wọ́ ní ìlú Makurdi, ìpínlẹ̀ Benue fún ìsìnkú àwọn èèyàn wọn tí àwọn afurasí Fúlàní daran daran pa.

Fadá méjì àti àwọn ọmọ ìjọ mẹ́tàdínlógún ní àwọn afurasí apànìyàn náà dá ẹ̀mí wọn légbòdò.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Sáájú, Gọ́mìnà Ortom ti kéde ọjọ́ ìsẹ́gun gẹ́gẹ́ bí ọjọ́ ìsinmi lẹ́nu isẹ́ láti se ẹ̀yẹ ìkẹyìn fún àwọn tó lọ.

Image copyright @CollinsUma
Àkọlé àwòrán Ẹkún sọ níbi ìsìnkú Fadá àtàwọn ọmọ ìjọ ní Benue

Bákan náà, ètò ìsìnkú yìí wáyé lẹ́gbẹ̀ẹ́ kẹ̀gbẹ́ ìwọ́de gbogbo ìjọ Àgùdà káàkiri orílẹ̀èdè Nàìjíríà.

Àfẹnukò láti se èyí wáyé níbi ìpàdé àwọn Bísọọ̀bù orílẹ̀èdè Nàìjíríà tí wọ́n ti pa á lásẹ fún gbogbo ọmọ ìjọ Àguda jákè jádò orílẹ̀èdè Nàìjíríà láti gùn le ìwọ̀de wọ́ọ́rọ́wọ́ pẹ̀lú àdúrà lọ́jọ́ ìsẹ́gun kan náà èyí tí wọ́n pe àkòrí rẹ̀ ní ''Yíyan fún ẹ̀mí".

Àkọlé àwòrán Ìwọ́de ìjọ Àgùda nílùú Eko
Àkọlé àwòrán Ìwọ́de ìjọ Àgùda nílùú Portharcourt

Olú ìlú orílẹ̀èdè Nàìjíríà náà kò gbẹ́yìn nínú ìpàdé àdúrà àti ìwọ́de náà.

Àkọlé àwòrán Ìwọ́de ìjọ Àgùda nílùú Abuja