Ìjọ Redeem: Á se àyẹ̀wò ojú ara fáwọn àfẹ́sọ́nà sáájú ìgbeyàwó

Olùsọ́àgùntàn Adejare Adeboye
Àkọlé àwòrán,

Ìgbésẹ̀ náà ló wà láti dènà ọ̀pọ̀ lààsígbò ló ń mi ìgbeyàwó lògbò-lògbò

Ìjọ Ìràpadà ti ẹ̀mi, táa mọ̀ sí The Redeemed Christian Church of God (RCCG) ti fi àtẹ̀jáde kan síta pé, láti àkókò yìí lọ, àwọn àfẹ́sọ́nà tó bá fẹ́ se ìgbeyàwó nínú ìjọ náà, ni wọn yóó máa se àyẹ̀wò fúń ṣáájú ìgbeyàwó lórí àwọn ohun to so rọ̀ mọ́ ìbálòpọ̀ àti ìbímọ wọn.

Àtẹ̀jáde náà, tí wọn fi síta ní ọjọ́ kẹwàá, osú karùn-ún ọdun 2018, èyí tí Olùsọ́ àgùtàn J F Ọdẹ́sọlá fọwọ́ síí, ní Alákóso ìjọ Redeem lágbàáyé, Olùsọ́ àgùtàn Adéjàre Adébóyè ló pàsẹ pé káwọn tó ń darí ìjọ máa se àyẹ̀wò náà fáwọn àfẹ́sọ́nà tó fẹ́ di tọkọ-taya nínú ìjọ náà

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àtẹ̀jáde náà ní, àwọn aláṣẹ ilé ìjọ́sìn náà wòye pé, ọ̀pọ̀ lààsígbò ló ń mi ìgbeyàwó lògbò-lògbò nítorí irọ́ pípa, pàápàá láti ipasẹ̀ àìjẹ́wọ́ ipò tí àgọ́ ara ìkọ̀ọ̀kan lọ́kọ-láya wà àti ìlera ìbísí wọn.

Àtẹ̀jáde náà wá pàsẹ fáwọn adarí ìjọ ní ẹkùn kọ̀ọ̀kan láti fi orúkọ sílẹ̀ tàbí dara pọ̀ mọ́ ilé ìwòsàn ìjọba kan tí wọn ní ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀, níbi tí wọn yóò ti máa se àyẹ̀wò ìlera fáwọn àfẹ́sọ́nà sáájú ìgbeyàwó.

Gbogbo aáyan BBC Yorùbá láti gbọ́ ti ẹnu Olùsọ́ àgùtàn J F Ọdẹ́sọlá ló já sí pàbó nítorí kò gbé ìpè wa lórí ẹ̀rọ ìbáraẹni sọ̀rọ̀.