Buhari: Ìwà èṣù pátápátá ni ìkọlù àti ìpànìyàn nípínlẹ̀ Benue

Posi awọ̀n ti wọn pa

Oríṣun àwòrán, Benue state government

Àkọlé àwòrán,

Ẹni to ba n pa eeyan ti sọ alaafia rẹ nu, o si ti di ẹni itanu ati ẹni ifib

Aarẹ Muhammadu Buhari ni ẹmi esu lo n gbe inu awọn to n pa eeyan ni ipinlẹ Benue.

Aarẹ woye ọrọ ninu ọrọ ibanikẹdun to fi ranṣẹ si ibi isinku awọn fada meji atawọn ọmọ ijọ mẹtadinlogun, ti awọn afunrasi apaniyan kan ṣekupa nipinlẹ Benue.

Igbakeji aarẹ, Ọjọgbọn Yẹmi Oṣinbajo, lo ṣoju fun aarẹ Muhammadu Buhari nibi eto isinku naa.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Nigba to n jiṣẹ ti Aarẹ Buhari ran an sibẹ, Ọjọgbọn Oṣinbajo ni, ijọba to wa lode bayi ko ni sinmi ninu ilakaka rẹ, lati rii pe opin de ba irufẹ iwa buruku bẹẹ.

"Iru eeyan wo ni yoo ji laarọ kutukutu pẹlu ipinnu lati gba ẹmi awọn eeyan ti ko lẹṣẹ kan lọrun. Dajudaju, iru eeyan bẹẹ ti sọ alaafia rẹ nu, o si ti di ẹni itanu ati ẹni ifibu."

Oríṣun àwòrán, @ProfOsinbajo

Àkọlé àwòrán,

Igbakeji aarẹ, Ọjọgbọn Yẹmi Oṣinbajo lo ṣoju fun aarẹ Muhammadu Buhari nibi eto isinku naa

Lara awọn to ba igbakeji aarẹ kọwọ rin lọ sibi eto isinku naa ni awọn minisita feto irinna, Rotimi amaechi pẹlu Minisita fọrọ okeere, Geoffrey Onyeama.

Ni ọjọ kejilelogun oṣu kẹrin ọdun 2018, lawọn agbebọn kan ti awọn eeyan funrasi pe wọn jẹ darandaran Fulani ṣọṣẹ ni ileto kan, ti wọn si pa eeyan mejidinlogun ninu eyi ti awọn alufaa ijọ aguda meji wa.

Bakanna ni aarẹ tun ṣeleri ati ṣawari awọn to ṣọsẹ naa, ati lati ṣe atunto ati atunkọ awọn ileto ti wọn ti ṣọṣẹ.