NMA Ọ̀sun: A fẹ́ sisẹ́, Johesu ni kò jẹ́

Dokita onisegun oyinbo
Àkọlé àwòrán,

Ẹgbẹ́ NMA fewe ọmọ mọ Johesu leti pe ko ma ba ẹnikan ja, maa fi ọwọ gun gbogbo ile ni imu

Ẹgbẹ àwọn dókítà iṣegun Òyìnbó, NMA, ẹ̀ka típínlẹ̀ Ọ̀ṣun ti jáwé ìkìlọ̀ ránṣẹ́ sí àwọn òṣìṣẹ́ elétò ìlera, to n jẹ́ JOHESU yanṣẹ́lodi pe, kí wọ́n maṣe gbe sàárà wọn kọja moṣalaṣi.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ninu atẹjade kan ti wọn fi ṣọwọ́ si BBC Yorùbá, lẹ́yìn ifọrọwerọ pẹl'awọn akọroyin nilu Osogbo, awọn dokita ọhun ni, àwọn ko ni ki àwọn òṣìṣẹ́ iṣegun o maa ṣe iyanṣẹlodi wọn nitori bi alaisan yoo ba ku ko y,ẹ ko ba aje jẹ fun alalapa o.

Alaga ẹgbẹ awọn dokita iṣegun Òyìnbó NMA nípínlẹ̀ Ọ̀ṣun, Dokita Tokunbọ Ọlajumọkẹ ni, idiwo ati idunmọhuru mọni tàwọn ọmọ ẹgbẹ́ JOHESU n ṣe fáwọn dokita ni ileewosan nla fasiti Obafemi Awolowo, OAUTH ni Ile-Ife ko kere, awọn ko si ni kawọ gbera mọ lẹyin eyi.

"Àwọn ọmọ ẹgbẹ́ JOHESU gbọdọ tẹle Ilana iyanṣẹlodi láì tẹ ẹtọ awọn òṣìṣẹ́ yoku mọlẹ nítorí ẹja kìí l'ẹ́ja lawo"

Àkọlé àwòrán,

A rọ ijọba lati pese eto aabo to peye fun àwọn dokita, aláìsàn àtàwọn òṣìṣẹ́ yòókù níléèwòsàn

Bakanna ni wọ́n yànnà-ná rẹ̀ pe, awọn dokita fẹ ṣiṣẹ ṣùgbọ́n awọn ọmọ ẹgbẹ́ JOHESU ni ileewosan nla OAUTH naa ni wọ́n n pagidínà ipese eto iwosan fun awon alaisan nibẹ.

"A gba awọn aláṣẹ ileewosan nla OAUTH lamọran, lati pese eto aabo to peye fun àwọn dokita, aláìsàn àtàwọn òṣìṣẹ́ yòókù níléèwòsàn naa, ki wọn si gba awọn òṣìṣẹ́ aṣèrànwọ míràn láti maa ba àwọn dókítà ṣiṣẹ itọju awọn aláìsàn nibẹ titi dìgbà tí iyanṣẹlodi naa yoo fi yanju."