Ẹgbẹẹgbẹrún ní oró ejò ń pa lọdọọdún

Ejo
Àkọlé àwòrán,

Àjọ tó ń mójútó ètò ìlera lágbàyé (WHO) tí fẹnukò pé oró ejò jẹ́ ọ̀kan lára ohun tó ṣe pàtàkì nínú ètò ílera àgbáye

Àjọ tó ń mójútó ètò ìlera lágbàyé (WHO) ni iṣẹ́ ń bẹ niwaju ìjọba orílẹ̀-èdè gbogbo lórí ìtọ́jú oró ejò sùgbọ́n ọ̀pọ̀ àwọn elétò ìlera kò kàákún

Wọn ní ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn ènìyàn ló ń kú lọ́dọọdún tí ọ̀pọ̀ sì di aláàbọ̀ ara nípàsẹ̀ oró tí ejò pọ̀ sí wọn lára lásìkò tó bù wọn jẹ.

Àkọlé àwòrán,

Fún ìdí èyí ni àwọn orílẹ̀-èdè lábẹ́ àjọ WHO ṣe fẹnukò láti sètò ọ̀nà láti dẹ́kun, tójú àtí láti ṣe gba ìsàkóso ìtójú oró ejò.

Àjọ elétò ìlèra àgbáyé sọ pé pẹ̀lú gbogbo ìnira tó ń bá ìṣẹ̀lẹ̀ náà rìn síbẹ, o jẹ́ ọkan lára etò ìlera tí ẹnikẹ́ni kò kọbiara sí.

Fún ìdí èyí ni àwọn orílẹ̀-èdè lábẹ́ àjọ WHO ṣe fẹnukò láti sètò ọ̀nà láti dẹ́kun, tójú àtí láti ṣe gba ìsàkóso ìtójú oró ejò.

BBC Yorùbá ṣe ìwádìí láti mọ ipò tí orílẹ̀-èdè Nàìjíríà wà lórí ìtójú àwọn tí ejò bùjẹ àti pé irú ètò wo ló wà nílẹ̀ fún wọn.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ìwádìí BBC Yorùbá

Dókítà Francis Duru ti ile-ìwòsàn LASU ní ìpínlẹ̀ Ekó ṣàlàyé ipò tí ìtójú ẹni tí ejò bùsan ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà wa

Ọ̀nà wo ní a lè gbà dá ejò olóró mọ̀:

  • kọ́kọ́ yẹ orí rẹ̀ wò: ọ̀pọ̀ ejò olóró máa ń ní orí onígun mẹ́ta
  • Ó máa ń ní àwọ̀ tó mọ́
  • Àwọn míràn máa ń wo inú ojú rẹ̀ (sugọn ní ọ̀pọ̀ igbà eyí kìí ṣe ẹ̀rí tó dájú)
  • Wo ihò tó wà láàárín ojú àti imú ejò náà
  • Ejò tó máa ń darapọ̀ mọ́ àyíká
  • Ṣe àyẹ̀wò ojú ibi tí ejò ti bùyàn jẹ tí ó bá ní ojú méjì