Abiyamọ fi ọmọ sínú ọkọ̀ wọlé lọ, lọ̀rọ̀ yíwọ́

Ọkọ ti o takiti naa
Àkọlé àwòrán,

Ọkọ Hyundai náà ń lọ fúnra rẹ̀ títí fò tí ó fi já sí inú kòtò ńlá kan nítórí pé arábinrin náà kò fa ìjanu ọkọ̀ ti ọlọ́wọ́.

Arábinrin kan ní Magodo, ní Ipinlẹ̀ Eko fi ọmọ rẹ̀ ọmọ ọdún méjì sílẹ̀ nínú ọkọ̀ wọ inú ilé lọ ko fi sare mu nkan, ni ọkọ̀ náà bá tàkìtì kí ó to jáde sita.

Agbẹnusọ fun ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ní Ipinlẹ̀ Eko, Chike Oti, ni ọpẹ́lọpẹ́ ikọ̀ RRS tí ó wà ní itosi ibẹ̀. Àwọn ni a gbọ́ pé ó dóòla ẹ̀mí ọmọ náà.

Oti ní ọmọ náà fi orí àti apá ṣèṣe bí ọkọ Hyundai náà ṣe ré títí fò tí ó sì já sí inú kòtò ńlá kan nítórí pé arábinrin náà kò fa ìjanu ọkọ̀ ti ọlọ́wọ́.

Òjú ẹsẹ̀ ni wọ́n gbé ọmọ nàá lọ silé ìwòsàn. Ó ń gba ìtọ́jú lọ́wọ́lọ́wọ́ báyìí.