Real madrid vs Liverpool: Sáré wo ohun tí ó yẹ kí o mọ̀ kí ìfẹsẹ̀wọnsẹ náà tó bẹ̀rẹ̀

Jẹẹsi Liverpool ati madrid

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Lati igba ti wọn ti yan an sipo gẹgẹ bii olukọni ẹgbẹ agbabọọlu real madrid, Zinedine Zidane ko tii fidirẹmi ninu ipele komẹsẹ o yọ

Igba kẹfa niyi ti awọn ẹgbẹ agbabọọlu mejeeji yii yoo maa waako ninu idije Champions league.

Ẹ jẹ ki a wo iroyin nipa ifẹsẹwọnsẹ awọn mejeeji de ipele yii.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Ìtàn ńlá ló wà láàárín ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lú Real Madrid àti Liverpool;

Bi ẹgbẹ agbabọọlu Liverpool ba bori loni, olukọni wọn, Joggen klopp yoo di olukọni ọmọ orilẹede Germany karun ti yoo gba ife ẹyẹ champions league.

Lati igba ti wọn ti yan an sipo gẹgẹ bii olukọni ẹgbẹ agbabọọlu real madrid, Zinedine Zidane ko tii fidirẹmi ninu ipele komẹsẹ o yọ idije Champions league kankan.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Igba kẹfa niyi ti awọn ẹgbẹ agbabọọlu mejeeji yii yoo maa waako ninu idije Champions league

Eyi ni igba kọkanlelọgbọn ti ẹgbẹ agbabọọlu Real Madrid yoo maa wọ ipele aṣekagba idije ajọ elere bọọlu ilẹ Yuroopu, UEFA.

Eyi ni yoo si jẹ igba ogun ti Liverpool yoo maa wọ ipele aṣekagba idije ajọ elere bọọlu ilẹ Yuroopu, UEFA.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Bi Liverpool ba bori loni, Joggen klopp yoo di olukọni ọmọ orilẹede Germany karun ti yoo gba ife ẹyẹ champions league

Salah ti gba bọọlu wọ awọn fun Liverpool ni igba mẹrinlelogoji ni saa yii. Iye kan naa ti Ronaldo ti gba wọle pẹlu.

Bi Ronaldo ba gba bọọlu wọ awọn loni, eyi ni yoo di aṣekagba kẹrin ti yoo ti maa ṣe bẹẹ.

Ṣaaju asiko yii, Ronaldo nikan ṣi ni agbabọọlu ninu itan to tii gba bọọlu wọ awọn ni ipele aṣekagba Champions League mẹta.

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Ṣaaju asiko yii, Ronaldo nikan ṣi ni agbabọọlu ninu itan to tii gba bọọlu wọ awọn ni ipele aṣekagba Champions League mẹta

O gbaa wọle ni ọdun 2008 nigba to wa pẹlu Manchester united, ni ọdun 2014 ati ọdun to kọja.

Ninu ifẹsẹwọnsẹ tọdun yii, Ronaldo lo ṣi n moke laarin awọn atamatase pẹlu goolu marundinlogun. Ohun kan ṣoṣo yii naa lo ṣi gba ayo to pọ ju eyi lọ ni saa kan ṣoṣo, iyẹn goolu mẹtadinlogun to gba wọ awọn bni saa champions league ọdun 2013-2014.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí: