Alaafin Lamidi Adeyemi's profile: Ọmọọba mẹ́wàá ló du òyè pẹ̀lú Adeyẹmi, tó sì já mọ́ ọ lọ́wọ́

Ọba lamidi Ọlayiwọla Adeyẹmi kẹta

Oríṣun àwòrán, @Alaafinofoyo

Àkọlé àwòrán,

Ọba Adeyẹmi gbafẹ, o gboge, to si rẹwa lọkunrin

Ọba Lamidi Ọlayiwọla Adeyẹmi Kẹta, pe ọdun mẹtalelọgọrin loke eepẹ ko to waja.

Bakan naa lo ti lo ọdun mejilelaadọta lori itẹ awọn baba nla rẹ ni ilu Oyo.

Oba nla ni ti gbogbo agbaye mọ ti wọn si n wari fun koda ko sẹni ti ko bọwọ fun un.

Gẹg bi aṣa, lootọ naa si ni, ko sẹni to lee wo o loju pẹlu arifin tori "iku baba yeye, alaṣẹ ekeji ooṣa ni Yoruba n pe e.

Oríṣun àwòrán, Alaafin Oyo/Facebook

Ojo ti n pa igun bọ, ọjọ ti pẹ ni ọrọ Ọba Adeyẹmi, tori pe oju rẹ ti ri ọpọ iriri sẹyin ko to jọba ati lẹyin to jẹ ọba tan.

Gẹgẹ bi a se ka loju opo Wikipedia lori itakun agbaye, kii kuku se aafin ọba ni wọn ti wo Ọba Adeyẹmi nigba to wa lewe, nitori pe a ri ka pe o ti gbe nilu Abẹokuta, Isẹyin ati Eko gan an ri.

Itan igbe aye Ọba Lamidi Ọlayiwọla Adeyẹmi Kẹta:

Oríṣun àwòrán, HRM Oba Lamidi Adeyemi 111

 • Ọmọ-Ọba ni Lamidi Ọlayiwọla, nitori inu idile Ọba Alowolodu nilu Ọyọ ni wọn ti bii, baba ati baba-baba rẹ si jẹ Alaafin pẹlu
 • Orukọ baba rẹ ni Ọba Adeniran Adeyẹmi keji, ẹni to wa lori itẹ, ki ijọba to rọ ọ loye nitori pe o n lọwọ ninu oselu sise
 • Ọjọ Kẹẹdogun, osu Kẹwaa, ọdun 1938 ni wọn bi Lamidi Ọlayiwọla, eyi tii se ọdun mejilelọgọrin sẹyin
 • Bi o tilẹ jẹ pe ọmọ ọba ni, sibẹ, wọn ko wo Lamidi kekere ninu aafin Ọyọ gẹgẹ bii ọmọ ọla, ilu Isẹyin lẹba Ọyọ ni wọn ti wo dagba, to si tun lọ sile keu nibẹ.
 • Lamidi Ọlayiwọla tun gbe ni ọdọ Alake tilẹ Ẹgba, Ọba Ọladepo Ademọla, ko to di pe wọn tun rọ Alake yii loye
 • O tun lọ gbe lọdọ Ọlọla-binrin Kofoworọla Abayọmi ladugbo Keffi, ni Ikoyi nilu Eko, to si lọ sile ẹkọ Mọda, Ọbalende Modern School
 • Lẹyin eyi lo morile ileẹkọ girama St.Gregory‘s College, Ọbalende
 • Imọ nipa isẹ Amofin lo wu Lamidi lati kọ nile ẹkọ fasiti kan nilu oyinbo, o ku ọjọ meji ti yoo tẹ ọkọ leti ni wọn rọ baba rẹ loye, ti ko si lee lọ mọ
 • Isẹ aayan laayo ti Lamidi kọkọ mu se nigba ewe rẹ ni isẹ adojutofo (Insurance), to si tun jẹ akọsẹ-mọsẹ abẹsẹkubiojo, bẹẹ si lo tun maa n se ere idaraya titi di akoko yii lai naani ọjọ ori rẹ
 • Ki Ọlayiwọla to gun ori itẹ awọn baba nla rẹ, iyawo meji lo ni, eyiun Olori Abibat Adeyẹmi, ti wọn n pe ni iya Dodo ati Olori Rahmat Adedayọ Adeyẹmi, ti wọn mọ si iya Ile koto.

Oríṣun àwòrán, @Alaafinofoyo

 • Orukọ Akọbi ọmọ Ọba Adeyẹmi ni Kudirat Akọfade Erediuwa, ẹni to ti jade laye bayii
 • Eeyan mẹwaa lo du itẹ Alaafin pẹlu Lamidi Ọlayiwọla lẹyin iku Alaafin Bello Gbadegẹsin Ladigbolu keji
 • Lara awọn to du ipo naa ni Arẹmọ Sanni Gbadegẹsin, Ọmọọba Ọlanitẹ Ajagba, Ọmọọba Afọnja Ilaka, Ọmọọba Sanda Ladepo Ọranlọla ati bẹẹ bẹẹ lọ
 • Ọjọ Kẹrinla, osu Kinni, ọdun 1971 ni Ọba Lamidi Ọlayiwọla gun ori itẹ awọn baba nla rẹ, to si di Ọba Lamidi Ọlayiwọla Adeyẹmi kẹta
 • Alaafin maa n sọla laarin awọn aya rẹ, paapaa awọn to jẹ ọdọ, ti wọn si tun jẹ oju ni gbese ni ọdẹdẹ, o si maa n mu wọn yangan lọ si ọpọ ibi to ba n lọ
 • Lara awọn arẹwa aya Alaafin ni Olori Ola, Memunat, Badrat ati bẹẹ bẹẹ lọ
Àkọlé fọ́nrán ohùn,

Alaafin Ọyọ: Asiri agbara bibi ibeji lọpọ igba

 • Ni ẹni ọdun mejilelọgọrin, Ọba Adeyẹmi ni okun ati agbara to ju tawọn ewe miran lọ, to si bi ibeji ni ẹẹmeji ati ibẹta
 • Onkọtan, Onpitan ati ọlọpọlọ pipe ni Alaafin, ti ko si gbagbe ọpọ itan ilẹ Yoruba ati Naijiria lai naani ọjọ ori rẹ
 • Lara awọn ọmọ Alaafin to gbaju-gbaja ni Amofin Babatunde, Ọmọọba Fọlasade, Taibat, Nurudeen Adesẹgun, Akeem Adeniyi (Skimmeh), Adebayọ Fatai ati bẹẹ bẹẹ lọ
 • Awọn ọmọ Alaafin kan ti di ipo oselu mu sẹyin, ti awọn miran si tun wa nipo oselu.
 • Lara wọn la ti ri Fọlasade ati Taibat ti wọn ti jẹ Kọmisọnna nipinlẹ Ọyọ nigba kan ri ati Akeem Adeniyi, to ti jẹ alaga ijọba ibilẹ ri, to tun lọ sile asofin apapọ ilẹ wa.
 • Ọba Adeyẹmi gbafẹ, o gboge, to si rẹwa lọkunrin.
Àkọlé fídíò,

Itan Ilu gangan

Lara oriki Alaafin ni:

" Iku baba yeye, Adeyẹmi Alowolodu, ojo pa sẹkẹrẹ ma dẹ, ọmọ Atiba, ọmọ iku ti iku ko gbọdọ pa, ọmọ arun ti arun ko gbọdọ se.

Oun lo n gbin agbado ọran sẹyinkule ẹlẹyinkule, ko gbọdọ ya a jẹ, bẹẹ ni ko gbọdọ tu u danu".

Oríṣun àwòrán, @Alaafinofoyo

Àkọlé àwòrán,

kekere ni Lamidi Adeyẹmi wa to fi gori itẹ awọn baba nla rẹ, ti ade si yẹ ẹ