Champions league: Real Madrid gba ife ẹ̀yẹ fún ìgbà kẹta ní tẹ̀lé ǹ tẹ̀lé

Awọn agbabọọlu real Madrid n yọ pelu ife wọn Image copyright AFP/Getty Images
Àkọlé àwòrán Real Madrid gba ife ẹ̀yẹ fún ìgbà kẹta ní tẹ̀lé ǹ tẹ̀lé

Ẹgbẹ agbabọọlu Real madrid ti gba ife ẹyẹ Champions league ti ọdun yii.

Ami ayo mẹta si ẹyọkan ni wọn fi gbẹyẹ mọ liverpool lọwọ ni papa iṣire Kiev.

Image copyright European Photopress Agency
Àkọlé àwòrán Real madrid ni ikọ̀ agbábọ́ọ̀lù àkọ́kọ́ tí yóò gba ife yìí fún sáà mẹ́ta tẹ̀léra

Kareem Bẹnzema lo kọkọ gba goolu wọle ni igba ti ifẹsẹwọnsẹ naa wọ iṣẹju kọkanlelaadọta ti aṣọle Liverpool ṣe aṣiṣe pẹlu bọọlu to fẹ ju si akọgbẹ rẹ.

Idamu ọkan bọ sagbo ikọ Liverpool nigbati ogunna gbongbo agbabọọlu wọn, Mohammed Salah ni lati jade kuro lori papa lẹyin ti o ti fi ejika rẹ ṣeṣe ninu itakangbọn pẹlu Sergio Ramos, Balogun ikọ Real Madrid.

Image copyright ALLSPORT/Getty Images
Àkọlé àwòrán Ifarapa Salah da idamu silẹ fun Liverpool

Laipẹ rẹ naa ni agbabọọlu Real Madrid, Dani Carvajal pẹlu jade nitori oun pẹlu fara ṣeṣe.

Ko pẹ pupọ lẹyin eyi ti Mane, agbabọọlu Liverpool daa pada.

Image copyright Reuters
Àkọlé àwòrán Gareth Bale lo tan bi oorun ni ifẹsẹwọnsẹ naa

Amọṣa ọrọ yi pada nigbati Gareth Bale gba ikeji wọle fun Real Madrid ni iṣẹju kẹrinlelọgọta ifẹsẹwọnsẹ naa, iyẹn iṣẹju mẹta lẹyin ti olukọni Real Madrid, Zinedine Zidane gbe e wọle.

Eyi ko dabi ẹni to Gareth Bale nitori isẹju kẹtalelọgọrin ifẹsẹwọnsẹ naa lo tun gba ayo miran wọle.

Image copyright Press Association
Àkọlé àwòrán Mane, ọmọ Senegal gba goolu wọle fun Liverpool

Gbogbo ija fitafita awọn agbọọlu Liverpool lo ja si pabo.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionLori papa iṣire Kiev ni aṣekagba idije Champions league yoo ti waye