May 27: Nàìjíríà se Àyájọ́ ọjọ́ àwọn èwe

Àwọn èwe Nàìjíríà
Àkọlé àwòrán,

Àyájọ́ ọjọ́ àwọn èwe lónìí

Skip Facebook post, 1

Content is not available

View content on FacebookBBC kò mọ̀ nípa àwọn ohun tí ó wà ní àwọn ojú òpó tí ó wà ní ìta.

End of Facebook post, 1

Ẹ̀rín ẹ̀ẹ̀kẹ́ àwọn èwe a máa mú 'nú ẹni dùn, ojú wọn bíi ti Ángẹ́lì a sì máa gbilẹ̀ nínú ọkàn ẹni.

Àyájọ́ ọjọ́ àwọn èwe lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà jẹ́ ọjọ́ tí wọ́n yà sọ́tọ̀ láti pọ́n àwọn èwe lé.

Ọjọ́ kẹtàlélógún, osú kárùn-ún, ọdún 1964 ni orílẹ̀-èdè Nàìjíríà kọ́kọ́ se ayẹyẹ àyájọ́ ọjọ́ àwọn èwe.

Àkọlé àwòrán,

Àyájọ́ ọjọ́ àwọn èwe lónìí

Lọ́dún tó kọja, ààrẹ́ Muhammadu Buhari ní a gbúdọ̀ ríi dájú wí pé àbò wa fún àwọn èwe Nàìjíríà.

Láti ìgbà náà ni ìjọba ti ya ọjọ́ náà sọ́tọ̀ fún síse àyájọ́ ọjọ́ àwọn èwe àti yíyẹ́ wọn sí láì ya ọmọ kan sọ́tọ̀.

Àkọlé àwòrán,

Àyájọ́ ọjọ́ àwọn èwe lónìí

Ní ọjọ́ ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni oníkálùkù orílẹ̀-èdè àgbáyé máa ń se ayẹyẹ àyájọ́ ọjọ́ àwọn èwe káàkiri àgbáyé.

Ọdún 1955 ni wọ́n kọ́kọ́ se àyájọ́ yìí lágbayé lábẹ́ onígbọ̀wọ́ àjọ́ àgbáye kan tó ń rí sí ìtọ́jú àwọn èwe, International Union for Child Welfare ní Geneva.

Àkọlé àwòrán,

Àyájọ́ ọjọ́ àwọn èwe lónìí

Ní ọdún 1954 ni ìpàdé ìgbìmọ̀ àjọ ìsọ̀kan àgbáyé kéde rẹ̀, wọ́n se ìfilọ́lẹ̀ rẹ̀ kí gbogbo orílẹ̀-èdè lè yan ọjọ́ kan fún ti wọn.

Lákọkọ́, wọ́n se ìfilọ́lẹ̀ rẹ̀ láti se ìmúgbòòrò ìgbọ́ra-ẹni-yé láàrín àwọn èwe.

Ẹ̀ẹ̀kejì, láti bẹ̀rẹ̀ ìgbésẹ̀ fún jíjẹ ànfàní àti síse ìtọ́jú àwọn èwe lágbayé.

Awọn iroyin miran ti ẹ le nifẹ si: