Oluwo: Ẹ má gbé ẹ̀kú eégún 1960, tó ń rùn wọ ààfin mi

Ara an egungun to jade ni ilu Iwo

Ilu Iwo, nipinlẹ Ọsun sọkutu wọwọ fun ajọyọ ọdun Egungun lọjọ Ẹti, eyi to jẹ arimaleelọ, awo pada sẹyin.Atọmọde ati agba lo tuyaya jade fun ajọyọ ọdun egungun tọdun yii, gẹgẹ bi iṣe wọn lọdọọdun nilu Iwo.Okanojọkan egungun lo wọ aṣọ alarambara lọ si ojude ọba lati ṣoju agbo ile wọn, bẹẹ ṣi ni gbogbo igboro ilu Iwo lo kun fọfọ fun ọgọrọ awọn eeyan to lọ fun oju lounjẹ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Bi awọn egungun kan ṣe n gbe odo lori, ni awọn mii n yọ atori, bakan naa sini awọn kan ninu wọn tun fa ọmọ lọwọ, lasiko ti wọn n ṣe afihan igbelaruge aṣa ilẹ Yoruba yii.

Ijọba lee pawo wọle lati ara ọdun egungun - OluwoNinu ọrọ rẹ pẹlu ikọ BBC Yoruba, Oluwo ti ilu Iwo, Ọba Abdulrasheed Adewale Akanbi, Telu kinni, ṣe alaye wipe akanṣe ọdun egungun naa jẹ nnkan iṣẹnbaye, ti o si tun jẹ nnkan ti wọn fi n da ọba lara ya.Kabiyesi ṣe afikun ọrọ wipe, ayipada ọtun ti de ba ọdun eegun naa, nitori ko si anfani fun egungun kankan lati wọ aṣọ idoti wa si aafin Ọba.

Oluwo tẹsiwaju wipe, eleyi yoo mu ki o rọrun fun tọmọde tagba lati sun mọ awọn egungun naa, dipo sisa fun wọn gẹgẹ bi nnkan ibẹru."Kosi eegun kan ti yoo wọ aafin mi to gbọdọ dọti. Kii ṣe wipe wọn yoo gbe ẹku 1960 wa, to ti dọti, to n run-un. Mo fẹ ki egungun to ba wa, jẹ nnkan iwuri fun awọn ọmọde ati awọn agba, ki gbogbo eeyan lee fi ọwọ kan awọn eegun yii."Kabiyesi tẹsiwaju wipe, ọdun egungun kii ṣe fun ibọriṣa, bikoṣe fun igbelaruge aṣa ati ere idaraya.

Awọn olukopa ni ọ̀dun egungun lọna abayọ si isoro araalu

Lara awọn olukopa nibi ajọdun naa, wa fi igbgabọ wọn han wipe, egungun ni agbara lati sọ gbogbo ibi ti o ba wa laarin ilu di rere lasiko ti wọn ba wọde.Wọn ri ere idaraya awọn egungun gẹgẹ bi etutu, ti yoo ṣe pese ọna abayọ si awọn oniruuru iṣoro bi airọmọbi, ailaya, oṣi, aini ati awọn iṣoro mii to le ma a ba awọn eeyan ilu finra.

Bakan naa ni wọn se alaye wipe, odun naa le mu owo to pọ wọle fun ijọba ipinlẹ Ọṣun lẹka irin ajo igbafe, ti wọn ba ṣe amojuto rẹ bi o ti tọ ati bi o ti ye.Botilẹ jẹ wipe 'ilu awọn alfa' ni ọpọlọpọ eeyan mọ ilu Iwo si, sibẹ lọdọọdun ni ajọdun egungun n gbilẹ sii.

Àkọlé àwòrán,

Ọba Adewale Akanbi ti ma ń sọ̀rọ̀ nípa ìfìmọsọ̀kan àwọn ẹ̀yà tó wà lórílẹ̀èdè Nàíjíríà

Yorùbá bọ wọn ní àrà kì tán ní ilé alárá.

Èyí dífá fún bí Oluwo ti Ilu Iwo, Ọba Abdulrosheed Adewale Akanbi, Telu 1 se ro dédé tí o sí kàn dudu nibi ayẹyẹ ti wọn ti n joye asiwaju awọn Igbo to wa ni ilu Iwo.

N'isẹ ní orí adé náà fakọyo pẹlu asọ ẹ̀yà Igbo to wọ nibi ayẹyẹ naa.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ọba naa to ti maa n sọ lọpọ igba wi pe ifọwọsọwọpọ ni ọna abayọ si ọpọlọpọ isoro to n koju orilẹede Naijiria, ni wiwọ asọ awọn Igbo fihan wi pe oun fẹran ifọwọsọwọpọ.

Ninu ọrọ rẹ, Ọba naa ni wi pe ‘awọn oun to n fa ẹlẹyamẹya ni ilẹ yii ni ọrọ sabuke ibi to ti wa(State of Origin Certificate ), ati ai le dije dupo ni ibi to ba ti wu o’.

Ọba Oluwo wa gba awọn ọmọ Naijiria ni iyanju lati ma a wọ asọ àwọn ẹya miiran lati le bu ẹwa kun orilẹede Naijiria.