Ìsèjọba Nàíjíríà: Bí ológun se lọ, ni alágbádá wọlé dé

Obafemi Awolọwọ, Abubakar Tafawa Balewa àti Nnamdi Azikwe nínú ìpàdé kan Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Nàìjírìa gba òmìnira ní ọjọ́ kínní oṣù kẹẹ̀wá ọdún 1960

Orilẹede Naijiria gba ominira lọwọ ijọba ilẹ Gẹẹsi ni ọjọ kinni osu kẹwa ọdun 1960.

Aarẹ akọkọ ni orilẹede Naijiria ni Nnamdi Azikwe, ti Abubakar Tafawa Balewa si jẹ Olori ijọba.

Naijiria di orilẹede olominira ni ọdun 1963.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionÀyájọ́ ọjọ́ ìjọba tiwa n' tiwa: Kókó 10 nínú ọ̀rọ̀ Buhari

Aarẹ Azikwe ati Olori ijọba Tafawa Balewa wa lori aleefa di ọdun 1966.

Ṣugbọn awọn ologun gba ijọba lọwọ rẹ l'ọdun 1966 kan naa.

Ọmọ ologun Chukwuma Kaduna Nzeogwu lo dari iditẹ gbajọba naa.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ọ̀gágun Aguiyi Ironsi ni olórí ìjọba oógun àkọ́kọ́ ní orílẹ́èdè Nàìjírìa

Awọn ologun bẹrẹ si ṣe ijọba orilẹede Naijiria lẹyin igbati olori ologun Aguiyi Ironsi gori aleefa .

Orilẹede Naijiria pada si ijọba awa-arawa ni ọdun 1979 nigbati olori ijọba ologun, ogagun Olusegun Obasanjo gbejọba fun ijọba alagbada.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Shehu Shagari Ààrẹ ilẹ̀ naijiria l'ọ́dún 1979

Alhaji Shehu Shagari, to soju ẹgbẹ oselu NPN lo jawe olubori ninu idibo gbogbo-gboo fun ipo aarẹ l'ọdun naa.

Aarẹ Shagari ṣe 'jọba fun ọdun mẹrin akọkọ, o si tun wọle fun saa keji ni ọdun 1983.

Ṣugbọn ko pẹ to wọle ni awọn ologun tun gbajọba, ti ọgagun Ibrahim Babangida si gori aleefa.

Awọn ologun ṣe ijọba orilẹede Naijiria di ọdun 1999, ki ijọba tiwa n tiwa to pada.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ajagun fẹ̀yìntì Olusegun Obasanjo di Ààrẹ orílẹ́èdè Nàìjírìa l'ọdún 1999

Ajagun fẹhinti Oluṣégun Obasanjo lo jawe olubori ninu idibo gbogbo-gboo fun ipo aarẹ bi Naijiria ṣe pada si ijọba awarawa l'ọdun 1999.

Ẹgbẹ oṣelu PDP lo wa lori aleefa fun ọdun mẹrindinlogun akọkọ, ki APC to gori oye l'ọdun 2015 nigbati Aarẹ Muhammadu Buhari bẹrẹ ijọba rẹ.

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ìjọba Ààrẹ Muhammadu Buhari di ọdún mẹ́ta l'ọ́jọ́ mọ́kàndínlọ́gbọ̀n oṣù karùn ún ọdún 2018

Ijọba Aarẹ Buahari pe ọdun mẹta l'ọjọ Iṣẹgun ọjọ kọkandinlọgbọn oṣu karun un ọdun 2018, ti i ṣe ayajọ ọjọ ijọba awarawa nilẹ Naijira.