Àyájọ́ tiwa n tiwa: Àríwísí gbòde lórí ọ̀rọ̀ Buhari

Aarẹ Buhari Image copyright @BashirAhmaad
Àkọlé àwòrán Ko fe si igba ti Aare Buhari sọrọ ti ko mu iriwisi wa lati ọdọ awọ́n ọmọ Naijiria

''A ti gba òpó agbègbè pada lọwọ Boko Haram, a rí owo fi pamọ́ ni idi didẹkun ayédèrú òṣìṣẹ́, kódà a tún rí eedegbeta biliọnu náírà gbà pàdà nípasẹ ètò atuni-laṣiri.''

Díẹ lára kọkọ ọ̀rọ̀ àpilẹ̀kọ Muhammadu Buhari ree, ní ayajọ́ ọjọ ìjọba tiwa n' tiwa.

Ààrẹ Buhari ka awọn aseyori ìjọba rẹ ṣugbọn ójú òpó Twitter ti kun nipa iriwisi àwọn ọmọ Naijirià

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Diẹ lara awọn ariwisi naa ree.

Ọ̀rọ̀ Leah Sharibu

Awọn ọmọ Naijiria n naka aleebu si aarẹ Muhammadu Buhari pe ko mẹnuba itusilẹ Leah Sharibu to si wa ni igbekun Boko Haram titi di akoko yii.

Wọ́n ló s'ẹnu mẹrẹ lórí ọrọ ìlera pẹlú bí àwọn oṣiṣẹ ìlera ṣe yí wà lẹnu idasesile

Bákannáà láwọn kan sọ oko ọrọ sí Aare Buhari pé lootọ ètò ìṣèjọba tiw n tiwa pé ọdún mokandinlogun gẹgẹ bí o tí ṣé sọ, ṣugbọn bi kíì ba ṣé wí pé àwọn kan fi ipa gba ìjọba lọdun 1983, kò bá ti ju bayii lọ.

Àwọn kàn kúkú ni kò sí nnkan tuntun nínú gbogbo ọrọ ti Buhari sọ, sugbọn nnkán to kọjú sí ẹnìkan, ẹyìn lo ko s'elomiran bii ilu Gangan.

Nkan tí Ààrẹ sọ ko ti è kan ẹlòmíràn. Ọrọ àsìá ti o ló níbi igbohunsafẹfẹ òhun lo jẹ wọn lógun.