Ikú kò jẹ́ ki Tunrayọ Adeoye ri òpin Ramadan

Tunrayo Adeoye Image copyright Kola carew Facebook
Àkọlé àwòrán Wọn ti sin Tunrayọ Adeoye ni ile rẹ nilana ẹsin musulumi ni ilu Ibadan

Gbajugbaja osere Nollywood, Motunrayo Adeoye, ti jade laye lasiko aisan ọgbe inu to ti n baa finra fun ọjọ gbọọrọ ni ilu Ibadan.

Iroyin jade pe, agba obinrin osere naa jade laye lowurọ Ọjọ Ẹti, ọjọ kinni, osu kẹfa.

Image copyright @naijapalsf/b
Àkọlé àwòrán Ọlọ́jọ́ dé fún Alhaja adeoye ninu ààwẹ̀ Ramadan

Wọn ti sin Tunrayọ Adeoye ni ile rẹ to wa ladugbo Akobọ ni ilu Ibadan, nilana ẹsin musulumi.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionỌmọge Campus: Lọla Alao ní Aisha ti ni àìsàn jẹjẹrẹ ti pẹ́

Nigba aye rẹ, obinrin naa jẹ gbajugbaja ninu ẹgbẹ osere Yoruba, ati wipe, o tun jẹ ọkan lara awọn ilumọọka ninu ẹgbẹ awọn osere.

Igbe aye Motunrayo Adeoye

Ni igba aye rẹ, Motunrayo jẹ ibatan alaafin ti Ọyọ, Ọba Lamidi Adeyemi kẹta.

Arabinrin naa kawe gboye ni ileẹkọ ẹkọsẹ ọwọ ti Osogbo Technical College ni ipinlẹ Osun, nibi to ti kọ nipa imọ ẹrọ, ki oto sẹ sẹ wa lo si orilẹede Switzerland fun Osu meje lati lo kọ ẹkọ gboye nipa imọ ẹrọ.

Lẹyin ọdun 1970 ni gbajugbaja osere naa darapọ mọ ile-isẹ iroyin ti ipinlẹ Ọyọ, BCOS gẹgẹbi onimọ nipa ẹrọ ati igbohunsafẹfẹ.

Image copyright Kola Carew Facebook
Àkọlé àwòrán Ọkan lara awọn ere ti Tunrayọ Adeoye se, to fi di ilumọọka ni fiimu kan ti wọn pe ni Igbekun.

Isẹ naa lo se fun ọgọji ọdun ko to di wi pe o fẹhinti lọdun 2010.

Lẹyin igba yi ni o darapọ mọ awọn olosere Nollywood., ọkan lara awọn ere to se to fi di ilumọọka ni fiimu kan ti wn pe ni igbekun.