England vs Nigeria; Ifẹsẹwọnsẹ naa gbona jainjain!

England naa Nigeria pelu ami ayo Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán England vs Nigeria; Ifẹsewonse na gbona jainjain!

Ikọ orilẹede England ti fagba han Naijiria pẹlu ami ayo meji si eyọkan ninu ifẹsẹwọnsẹ ọlọrẹsọrẹ lati se igbaradi fun Idije Ife Ẹyẹ Agbaye Russia 2018.

Iko agbabọọlu England bẹrẹ ifẹsẹwọnsẹ naa pẹlu bi Cahill ti ẹgbẹ agbabọọlu England se fi ori gba bọọlu sinu awọn ni isẹju meje ti ifẹsẹwọnsẹ naa bẹrẹ ni papa isere Wembley ni ilu London, lẹyin naa ni Harry Kane fi ẹyọkan si ni saa kini.

Isẹju meji lẹyin ti wọn wọle fun saa keji ni Alex Iwobi ti ẹgbẹ agbabọọlu Naijiria da omi ayo kan pada sinu awọn, eyi to fi agbara fun ikọ Super Eagles lati pegede ni saa keji ifẹsẹwọnsẹ naa, ti ifẹsẹwọnsẹ naa si pari si 2-1.

Ẹlẹẹkẹta ni yii ti ikọ mejeeji yoo ma pade, lẹyin ti wọn koju ara won ni ọdun 2002 ninu Idije Ife Ẹye Agbaye ti ọdun naa.

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media captionKini o mọ nipa igbaradi Super Eagles?

Nàìjíríà yoo koju Czech Republic ni Ọjọọru, Ọjọ Kẹfa, Oṣu yii, gẹgẹbi ifẹsẹwọnsẹ tọo ṣaaju Idije Ifé Ẹyẹ Agbaye, Russia 2018.