Forbes Africa: Davido, Wizkid, Falz kogoja lẹ̀ka amuludun ní Áfíríkà

Davido, Wizkid ati Falz Image copyright AFP
Àkọlé àwòrán Forbes kan sara si Davido, Wizkid ati Falz lori ipa ti wọn n ko lẹ amuludun

Iwe atigbadegba agbaye kan, Forbes Africa ti tọka si awọn gbajugbaja onkọrin ọmọ orilẹede Naijiria kan gẹgẹ bii ara awọn ọdọ ti o lamilaaka julọ lẹnu iṣẹ ti wọn yan laayo nilẹ Afirika.

Awọn onkọrin taka-sufe hip-hop, Davido pẹlu Wizkid wa alara awọn ọmọ orilẹede Naijiria ti Forbes Africa tọkasi gẹgẹ bii wọọ kilumọ ti wọn n dabi ẹdun, rọ bi owe lẹka iṣẹ ti wọn yan laayo.

Ẹka mẹta ni wọn pin awọn ti wọn kede si, ẹka ọgbọn atinuda, imọ ẹrọ ati oowo.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ọmọ Prof. Peller gbé 'gbá ìbò fún 2019

Salah yóò pàpà lọ sí ìdíje Àgbáyé

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media caption'Èmi ò kí ń lu ìyàwó mi'

Awọn miran ti wọn tun darukọ ni Falz, Sarkodie, Nasty C, Cassper Nyovest, Falz, Yemi Alade, Beverly Naya, Sonia Irabor ati bẹẹbẹẹ lọ.

Bakanna ni wọn tun mu awọn oludalee'sẹ aṣaraloge silẹ bii Adebayo Oke-Lawal ati Tania Ọmọtayọ, Anita Adetola Adetoye ati Joyce Jacobs pẹlu.