June 12: Lai Mohammed ni Buhari ti wo ọgbẹ́ June 12 sàn

June 12: Lai Mohammed ni Buhari ti wo ọgbẹ́ June 12 sàn

Mínísítà fétò ìròyìn, àsà àti ìrìnàjò afẹ́, Alhaji Lai Muhammed, lásìkò tó ń bá BBC Yorùbá sọ̀rọ̀ ní ààrẹ Buhari ri pé ohun tó tọ́, tó sì yẹ ni láti fi ẹ̀yẹ yìí dá MKO Abiọla.

Ó ní tó bá jẹ́ pé ààrẹ Buhari ń fi ọ̀rọ̀ yìí se òsèlú tàbí fa ojú àwọn èèyèn mọ́ra ni, kí ló dé tí àwọn ààrẹ tó ti kọjá lọ kò se ti se bẹ́ẹ̀.

Lai Muhammed wá kéde pé láti àkókò yìí lọ, ojú ààrẹ ni wọn yóò fi máa wo MKO Abiọla nítorí ààrẹ nìkan ni wọ́n ń fi oyè GCFR dá lọ́lá.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí: