Buhari ṣètò ìṣínu ààwẹ̀ pẹ̀láwọn amúlúdùn Nàìjíríà l'Abújá

Awọn Image copyright Nigeria Presidency
Àkọlé àwòrán Àwọn òṣèrè àti olórin káàkiri Nàìjíríà ni wọ́n kópa nínú ètò àpèjẹ ìṣínu àwẹ̀ pẹ̀lu Ààrẹ nílú Àbújá

Awọn gbajugbaja amuludun ọmọ Yoruba ṣinu ààwẹ pẹlu Buhari

Díẹ̀ lara wọn ni: Kunle Afọlayan, Temitope Adekunle ti ọpọ mọ si Small Doctor, Tobi Bakare (Big Broda Naija), Olanrewaju Fasasi ti pupọ eeyan mọ si Sound Sultan atawọn oṣere tiata ati olorin ọmọ Yoruba ni wọn kọwọrin lọ ba Aarẹ Muhammed Buhari ṣinu awẹ l'Ọjọbọ ni ile aarẹ, Aso Rock Villa nilu Abuja.

Awọn amuludun ọmọ Yoruba naa wa lara awọn amuludun kaakiri orilẹ-ede Naijiria ti Aarẹ Buhari ranṣẹ si lati wa ba oun ṣe apejẹ iṣinu awẹ fun Ọjọbọ.

Image copyright Nigeria Presidency
Àkọlé àwòrán Awọn amuludun kan sara si Buhari

Awọn miran to tun jẹ ọmọ Yoruba to wa nibi iṣinu aawẹ naa ni, Adebayọ̀ Salami ti gbogbo eeyan mọ si Ọga Bello, Ali Jita, ati olukopa eto agbelewo mohunmaworan ni, BB Naija, Tobi Bakare.

Ṣaaju apejẹ pẹlu awọn amuludun jakejado Naijiria wọnyii, Aarẹ Buhari ti ṣinu aawẹ pẹlu awọn adari ile aṣofin apapọ, awọn odu oniṣowo lorilẹ-ede Naijiria atawọn ọba alaye titi kan awọn olori ẹka ẹsin gbogbo.

Ninu ọrọ rẹ, Kunle Afolayan dupẹ lọwọ aarẹ fun anfani to fun awọn ọdọ ati amuludun lati baa ṣe jijẹ-mimu pọ lasiko aawẹ Ramadan.

Bakan naa ni gbajugbaja olorin, small doctor, pẹlu ko le pa idunnu rẹ mọra pẹlu bi o ṣe lọ sori ikanni twitter rẹ lati kọ bi inu rẹ ṣe dun to fun anfani naa.

Image copyright BashirAhmad
Àkọlé àwòrán Small Doctor dunnu lori apejẹ rẹ pẹlu Buhari

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media caption'Èmi ò kí ń lu ìyàwó mi'