June 12: Ògùn, Ọ̀yọ́, Ọ̀sun, Èkìtì kéde ìsinmi lẹ́nu iṣẹ́

Àwòran àwọn Gómìnà Gúúsù-Ìwọ̀ Oòrùn Nàìjíríà Image copyright @akinwumiambode
Àkọlé àwòrán Ìpínlẹ̀ Ògùn, Ọ̀sun, Èkìtì àti Ọ̀yọ́ kéde ìsinmi lọ́jọ́ kejìla, oṣù Kẹfà.

Àwọn ìpínlẹ̀ tó wà ní apá Gúúsù-Ìwọ̀ Oòrùn orílẹ̀èdè Nàìjíríà, Ògùn, Ọ̀sun, Èkìtì àti Ọ̀yọ́ kéde ọjọ́ kejìlá, oṣù Kẹfà gẹ́gẹ́ bí ọjọ́ ìsinmi lẹ́nu iṣẹ́.

Níbi ìpàdé tí àwọn Gómìnà ìpínlẹ̀ Mẹ́rẹ̀ẹ̀rin náà se ni ọ̀rọ̀ yìí ti jáde.

Ní ti ìpínlẹ̀ Ògùn, ó jẹyọ nínú àtẹ̀jáde kan tí akọ̀wé fún ìjọba ìpínlẹ̀ nàá, Taiwo Adeoluwa fọwọ́ sí.

Image copyright http://ogunstate.gov.ng
Àkọlé àwòrán Wọ́n ni ọjọ́ nàá yó le fún àwọn aráàlú ní ànfàání láti ṣe àjọyọ̀ ọjọ́ ìṣèjọba àwaarawa.

Nínú àtẹ̀jáde nàá tó tẹ ìwé ìròyìn Punch lọ́wọ́, wọ́n ni ọjọ́ nàá yó le fún àwọn aráàlú ní ànfàání láti ṣe àjọyọ̀ ọjọ́ ìṣèjọba àwaarawa.

Ààrẹ Buhari yóò ṣàbẹ̀wò sí Morocco

Àwọn ọ̀rọ̀ àyọlò MKO Abiọla

Yemi Osinbajo: Ìgbákejì Ààrẹ tó gbọ́ nípa ẹ̀!

Ọjọ́ nàá ẹ̀wẹ̀, ni wọ́n yòó tún fi ṣe àjọyọ̀ oyè GCFR tí Ààrẹ Muhammadu Buhari fi dá olóògbé MKO Abiọ̀la lọ́lá láìpẹ́ yìí.

Nínú ìròyìn mi, ìjọba ìpínlẹ̀ Ọyọ nàá ti kéde ọjọ́ nàá ní ọjọ́ ìsìnmi.

Ṣáàjú ni ìjọba àpapọ̀ tí fi ìkéde kan síta pé kò ní sí ìsìnmi fún àyájọ́ ọjọ́ ìṣèjọba àwaarawa.