#EndSARS: Shogunlẹ ní ẹ̀sùn ìdigunjalẹ̀, ìjínigbé ni FSARS yóò mójútó

SARS

Ileeṣẹ ọlọpa Naijiria ti ṣetan lati maa ṣe ayẹwo ọpọlọ ati awọn ayẹwo ara mi i fun awọn oṣiṣẹ FSARS.

Ọga agba ọlọpaa kan, Abayọmi Shogunlẹ lo fi ikede naa sita, l'oju opo ikansiraẹni Twitter rẹ.

O ni nitori aṣẹ atunto ti igbakeji aarẹ Naijiria, Ọjọgbọn Yẹmi Ọṣinbajo pa, lasiko to fi jẹ adele Aarẹ, o ti di dandan fun gbogbo ọlọpa FSARS lati maa wọ aṣọ toke-tilẹ aṣọ ileeṣẹ ọlọpa, titi di igba ti ọga agba ileeṣẹ ọlọpa, yoo fi buwọlu aṣọ iṣẹ tuntun fun FSARS.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àkọlé fídíò,

Lush Beauties: Ẹ má jẹ́ k‘ójú tìyín torí pé ẹ sanra, ẹ jáde síta

Awọn aṣẹ tuntun yii lo jẹyọ nibi ipade ijiroro kan ti igbimọ to wa fun atunto FSARS ṣe lọjọ Abamẹta.

Shogunlẹ tun jẹ ko di mimọ pe, "igbesẹ yoo bẹrẹ ni kiakia lati mu adinku ba awọn to wa ni ihamọ FSARS jake-jado Naijiria."

Ati wi pe, "awọn ẹsun adigunjale ati awọn ajinigbe nikan ni awọn oṣiṣẹ FSARS yoo maa mojuto."

O fi kun ikede naa pe, wọn yoo ko gbogbo awọn oṣiṣẹ FSARS ti ko koju oṣuwọn, lọ si ẹka mi i nileeṣẹ ọlọpa, ti wọn yoo si gba awọn akikanju mi i lati rọpo wọn.

xxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxxx

Ọlọ́pàá Sars bíi ọgọ́fà fẹ́ sá kúrò ní Èkó

Ninu iroyin mi i ẹwẹ, n se lawọn osisẹ ọlọpaa to wa ni ẹka to n gbogun tiwa idigunjale, SARS, ti wọn to ọgọfa niye, ti n kọwe beere pe ki isẹ gbe awọn kuro ni ipinlẹ Eko lọ si ipinlẹ miran, nitori ofiin tuntun kan ti ijọba se.

A gbọ pe eyi ri bẹẹ nigba ti asẹ kan wa lati olu ileesẹ ọlọpaa ilẹ wa nilu Abuja pe atunto kanmọ-n kia gbọdọ bẹrẹ ni ẹka Sars yii.

Ofin tuntun naa, ti wọn fi ransẹ si gbogbo ẹka ileesẹ ọlọpaa ilẹ wa lo pasẹ peayipada nla ti ba ẹka Sars nileesẹ ọlọpaa.

Àkọlé fídíò,

SARS ti bẹ̀rẹ̀ ìgbésẹ̀ láti yọ àwọn ọ̀bàyéjẹ́ kúro

Ofin naa ni "lati akoko yii lọ, awọn osisẹ Sars ko gbọdọ wọ asọ dudu ti wọn maa n wọ bii asọ isẹ mọ,amọ wọn gbọdọ bẹrẹ si wọ asọ ọlọpaa bayii, ti wọn si gbọdọ maa so orukọ wọn mọ igba aya wọn, to fi mọ nọmba wọn ninu isẹ ọlọpaa, ipo ti wọn wa ati ami idamọ wọn bii osisẹ ọlọpaa."

Asẹ naa to wa lati ọdọ ọga agba pata fun ileesẹ ọlọpaa ilẹ wa, Ibrahim Idris, tun fewe ọmọ mọ awọn osisẹ Sars leti pe eyikeyi ninu wọn, to ba kọ eti ikun si asẹ tuntun naa yoo jẹ iyan rẹ ni isu, ti oga to n sisẹ labẹ rẹ naa yoo si ru igi oyin.

Gẹgẹ baa ti gbọ, asẹ yii lo mu ki ọga ọlọpaa ni ipinlẹ Eko, Edgal Imohimi, pasẹ fawọn osisẹ Sars to wa labẹ rẹ lati tete gbe asọ ọlọpaa wọ, eyi ti ko ba awọn osisẹ naa lara mu, ti wn si n beere pe ki isẹ tete gbe awọn kuro ni ipinlẹ Eko ni kia-kia.

Alaye awọn osisẹ Sars naa, gẹgẹ bi a se gbọ ni wipe, ko ni lee rọrun fun awọn lati maa fi asọ ọlọpaa le awọn adigunjale tabi awọn ajinigbe. Wọn ni eyi yoo mu ki awọn ọdaran tete da awọn mọ, to si tun lee se okunfa iku ojiji fun awọn.

"Bi igba ti a fẹ mọọmọ gba ẹmi ara wa ni taa ba n wọ asọ ọlọpa lati le awọn ọdaran. Ko si ẹni to fẹ ku