June 12: Àwọn Ẹgba àti Owu ní ojúṣe Abiola yọ sílẹ̀ lẹ́yìn ọ̀pọ̀ ọdún tó jáde láyé

June 12: Àwọn Ẹgba àti Owu ní ojúṣe Abiola yọ sílẹ̀ lẹ́yìn ọ̀pọ̀ ọdún tó jáde láyé

Ilé Ààrẹ tí Abiọla ń kọ́ lọ l'Abẹokuta ti di ọgbà wèrè báyìí.

Moshood Kashimaawo Olawale Abiola ni wọn bi nilu Abẹokuta nipinlẹ Ogun lọdun 1937.

O díje fun ipo aarẹ lọdun 1993 pẹlu Babagana Kingibe gẹgẹ bii igbakeji rẹ níní idibo ti àwọn eniyan Naijiria gba pe o dara julọ.

Àkọlé àwòrán,

Iku ba ọla Abiola jẹ́

L'ọdun 1994 lo kede ará rẹ gẹgẹ bii aarẹ Naijiria ni eyi ti wọn fi fi Abiọla satimọle nibi to ti pada jẹ Olorun nipe.

MKO ku ni ọjọ keje, oṣu keje, ọdun 1998 satimọle.

Aarẹ Mohammadu Buhari fi oye Naijiria to ga julọ (GCFR) da Abiọla lọla lọjọ kejila, oṣu kéfa, ọdun 2018 yii.

Àkọlé àwòrán,

Buhari fun Abiola ni oye GCFR to ga julọ ni Naijiria lọdun 2018

Àwọn olùkòpá nínú ìdìbò June 12 1993 sọ ọ́ di mímọ̀ pé ó jẹ́ ìgbà àkọ́kọ́ tí ìdìbò lọ déédé láàrin Hausa, Igbo àti Yorùbá.

Ki Abiọla to ku lo ti n kọ ile Aarẹ si Abẹokuta eyi to ti di àkọ́tì bayii.

Àkọlé àwòrán,

MKO Abiọla, ọ̀pọ̀ eniyan lo n ṣelédè lẹyin rẹ

Ikú Abiọla ni ọpọlọpọ gba pe kìí ṣe àmúwá Ọlọrun rara nitori pe wọn ni wọn paá satimọle ni.

Awọn ènìyàn Naijiria kò lè tètè gbagbe Baṣọrun Kashimaawo Olawale Abiọla fún iṣẹ ribiribi to ṣe silẹ ki ọlọjọ to de.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí: