Ilé ẹjọ́ dín ẹ̀wọ̀n Joshua Dariye, Jolly Iyame kù sí ọdún mẹ́wàá

Gomina Dariye

Oríṣun àwòrán, EFCC

Àkọlé àwòrán,

Ilé ẹjọ́ gíga kan ní Abuja lo rán gomina ana ni Ìpínlẹ̀ Plateau, Sẹ́nétọ̀ Joshua Dariye lọ ẹ̀wọn ọdún mẹ́rìnlá tẹ́lẹ̀

Lẹyin ti o ti ile ẹjọ giga ti kọkọ ran an lọ si ẹwọn ọdun mẹrinla tẹlẹ de, ile ẹjọ kotẹmilọrun nilu Abuja ti din ẹwọn gomina ipinlẹ Plateau tẹlẹ, Joshua Dariye ku si ọdun mẹwa.

Ni oṣu kẹfa ọdun yii ni ile ẹjọ giga kan sọ Dariye si ẹwọn ọdun mẹrinla lẹyin to ni o jẹbi ẹsun didari owo ilu ti o din diẹ ni biliọnu meji naira, (N1.62billion) owo to yẹ fun lilo lori amojuto ajalu ayika ni ipinlẹ Plateau.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ile ẹjọ kotẹmilọrun naa ni lootọ ni ile ẹjọ giga naa gbe idajọ to tọ kalẹ nipa dida Dariye lẹbi ẹsun naa, ṣugbọn o ni niwọn igba ti o jẹ wi pe igba akọkọ niyi ti yoo di ero ile ẹjọ ko yẹ ki ile ẹjọ giga o fun un ni idajọ ti o pọ to bẹẹ.

Ni ọjọ kejila oṣu kẹfa ni ile ẹjọ giga kan ni olu ilu orilẹede Naijiria, Abuja labẹ onidajọ Adebukọla Banjoko ran Dariye, ẹni to jẹ sẹnetọ nile aṣofin apapọ lọ si ẹwọn ti o si ni o jẹbi ẹsun marundinlogun ninu mẹtalelogun ti wọn fi kan an.

Gómìnà àná míì, Joshua Dariye, tún rẹ́wọ̀n he

Oríṣun àwòrán, Joshua Dariye Chibi/Facebook

Àkọlé àwòrán,

Sẹ́nétọ̀ Joshua Dariye lọ ẹ̀wọn ọdún mẹ́rìnlá fún kíkó owó ìlú jẹ nígbà tó wà ní ipo gómínà ìpínlẹ̀ Plateau

Ilé ẹjọ́ gíga kan ní Abuja ti rán gomina ana ni Ìpínlẹ̀ Plateau, Sẹ́nétọ̀ Joshua Dariye lọ ẹ̀wọn ọdún mẹ́rìnlá, fún kíkó owó ìlú jẹ nígbà tó wà ní ipo gómínà.

Adájọ Adebukola Banjoko ní, Dariye jẹ̀bi ẹ̀sùn márùndínlógún nínú mẹ́tàlélógún lẹ́yìn tó gbọ́ ẹ̀bẹ̀ agbẹjọ́rò rẹ̀, Paul Erokor pé kí wọ́n ṣàánú fun-un.

Wákàtí mẹ́fà àti ààbọ̀ ni adájọ́ náà fi ka ìdájọ́ rẹ̀. Lẹ́yìn ò rẹyìn, o ní Dariye jẹ̀bi sise wọ̀bìà owo.

Agbẹjọ́rò fàjọ EFCC, Rotimi Jacobs, tako ẹ̀bẹ̀ agbẹjọ́rò Dariye, tó sì sọ fún ilé ẹjọ́ pé, kí wọ́n fun ní ìdaájọ́ tó lágbára jù.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí: