Ẹbí Adélékè: Wọ́n ti ti òṣèlú bọ ikú Ísíakà Adélékè

Aworan Isiaka Adeleke

Oríṣun àwòrán, @IsiakaAdeleke1

Àkọlé àwòrán,

Awọn mọlẹbi Adeleke ni awọn oloṣelu ti n fi ọrọ iku rẹ ṣe ọrọ oṣelu.

Awuyewuye to n rọgba yi iku gomina ipinlẹ Ọṣun nigbakan ri, Sẹnetọ Isiaka Adeleke, ko dabi eyi ti yoo jẹ rodo lọ mumi laipẹ

Awọn mọlẹbi oloṣelu naa ti kede pe awọn oloṣelu ti n fi ọrọ iku rẹ ṣe ọrọ oṣelu.

Wọn ni loju awọn, bi wọn tun ṣe mu nọọsi kan to n ṣetọju oloogbe naa nigba aye rẹ, Alfred Aderibigbe, eleyi ti ijọba ipinlẹ naa n ba ṣe ẹjọ lori iku Sẹnetọ Adeleke jẹ ara ọna ti ijọba ipinlẹ naa n gba lati da ewe rabata bo ohun ti wọn pe ni ootọ nipa iku oloogbe Adeleke.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

"Ijọba ko jẹ ki ẹbi ologbe o ri abajade iwadii ohun to paa latọdọ awọn dokita iṣegun oyinbo.

Bakan naa ni wọn ko fi abajade iwadii ile ẹjọ ti wọn gbe kalẹ lori iku rẹ han nibi ti wọn ti sọ pe oogun ti nọọsi naa lo fun oloogbe Adeleke lo ṣokunfa iku rẹ"

Awọn ẹbi Adeleke, ninu ọrọ kan ti wọn sọ ni ile oloogbe naa to wa nilu Ẹdẹ, ṣalaye pe bi ijọba ṣe tun ji giri lọsan kan, oru kan, lori ọrọ naa mu ọwọ kan ifura dani fun awọn.

Amọṣa, ijọba ipinlẹ Ọṣun ko tii sọ ọrọ kan lori eyi.