Ilé aṣòfin Èkìtì lé aṣofin Akinniyi fún ẹ̀sùn oorun sísùn

Ọkunrin kan n sun

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán,

Wọ́n tún fi ẹ̀sùn kan aṣòfin náà pé ó ń dún mọ̀huru-mọ̀huru mọ́ àwọn akẹgbẹ́ rẹ̀

Awọn aṣofin ipinlẹ Ekiti ti ke si ọkan ninu wọn pe ko lọ rọọkun nile fun igba diẹ

Wọn fi ẹsun igbesumọmi ati oorun àsùnjù kan an pe oorun rẹ pọju laarin ọdun mẹta to ti wa nile igbimọ aṣofin naa.

Aṣofin Sunday Akinniyi to n ṣoju ẹkun keji Ikẹrẹ lawọn aṣofin akẹgbẹ ni awọn ko gbọdọ gburo rẹ ni agbegbe gbagede ile igbimọ aṣofin ipinlẹ naa.

Alaga igbimọ to n ri si iroyin nile aṣofin naa, Ọmọwe Samuel Ọmọtọṣọ, ni ile gbe igbesẹ naa lẹyin ọpọlọpọ ifisun lati ọwọ olori ọrọ iṣẹ gbogbo nile aṣofin ọhun, Aṣofin Tunji Akinlẹyẹ ati abajade iwadii kan ti igbimọ ile naa ṣe.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

"Aṣofin yii kii ye sa nibi ijoko ile; paapaa lasiko ti ọrọ to kan ẹkun idibo to n ṣoju fun ba wa fun ijiroro.

Igba gbogbo ni awọn eeyan ẹkun rẹ maa ń fi ẹsun rẹ lọ niwaju ile lọpọ igba ṣugbọn ko yipada."

Bakan naa ni wọn tun fi ẹsun kan aṣofin Sunday Akinniyi pe o n dun mọhuru mọ awọn aṣofin ile naa, ti gbogbo ile si ti ni ki akọwe agba ile aṣofin ipinlẹ Ekiti o fi ẹjọ rẹ sun lọdọ awọn agbofinro gbogbo nipinlẹ naa.

Oríṣun àwòrán, facebook/Ekiti state government

Àkọlé àwòrán,

Wọn ti kọkọ yọ aṣofin Akinniyi ni ipo gẹgẹ bii akojanu ile loṣu karun un lati fi faa leti pé boya yoo yiwa pada

Alaga igbimọ to n ri si iroyin nile aṣofin naa. Ọmọwe Samuel Ọmọtọṣọ, tun ṣalaye pe wọn ti kọkọ yọ aṣofin Akinniyi ni ipo gẹgẹ bii akojanu ile loṣu karun un lati fi faa leti pe boya yoo yiwa pada.

"Dipo ko yi pada oorun ni aṣfin Akinniyi maa n sun niwọnba akoko perete to ba farahan nile aṣofin yii ti gbogbo awọn eeyan ti wa fun un ni inagijẹ 'Aṣofin oloorun' nitori eyi."

Oríṣun àwòrán, Facebook/Ekiti state government

O ni ọpọ igba ti olori ileegbimọ aṣofin ile naa ti gbaa niyanju pe ko mojuto ifẹ awọn eeyan rẹ pẹlu itọju alaafia aara rẹ lo ti fi ẹyin ọwọ yi danu.