World Cup 2018:Super Eagles ti kẹ́kọ̀ọ́ nínú ìdíje tó kọjá

World Cup 2018:Super Eagles ti kẹ́kọ̀ọ́ nínú ìdíje tó kọjá

Ọmọwe Rafiu Ọladiipọ to jẹ aarẹ ẹgbẹ aṣatilẹyin fún Super Eagles ni Naijiria kìí kọjá ipele keji ni idije agbaye tẹlẹ

O ba BBC Yorùbá sọrọ lori ìjà to wa laarin awọn aṣatilẹyin fun Super Eagles tẹlẹ, eyi to ti di afiẹyin ti eegun n fiṣọ bayii.

Gbogbo wọn ni wọn jọ n lọ si Russia fun aṣeyọri Super Eagles.

Ọmọwe Rafiu gba pe Super Eagles yoo de ipele keji, o kere tan ninu idije Russia 2018 to n bẹrẹ loni.

Bakan naa lo sọrọ lori ẹkọ ti awọn agbabọọlu Naijiria ti kọ ninu awọn idije ọlọrẹsọrẹ ti wọn ti kopa sẹyin.

Orilẹ ede Naijiria yoo koju Croatia lọjọ Abamẹta to m bọ laago mẹjọ alẹ́.

Oni ni idije agbaye, Russia 2018 yoo bẹrẹ