Shehu Sani: Buhari yẹ kó foyè dá àwọn akọni tókù lọ́lá pẹ̀lú

Sheu Sani

Oríṣun àwòrán, Sheu Sani /twitter

Àkọlé àwòrán,

Ken Saro Wiwa, Sheu Musa Yaradua àti àwọn mííràn nílo ìfoyèdánilọ́lá

Senetọ Shehu Sani ti kede pe o yẹ kí ààrẹ Muhammadu Buhari bẹ idile àwọn ogoni to sọ ẹ̀mí wọn nu wò.

O mẹnuba awọn bii Ken Saro Wiwa, Sheu Musa Yaradua, Bẹẹkọ Kuti, àti Chinma Ubani nítorí àwọn náà kú fún ìjọba awa-ara-wa.

Senetọ Sheu Sani, tó n sojú ẹkùn aarin gbùngbùn Kaduna, ló kàn sí ààrẹ Buhari bẹ́ẹ̀ lórí ìkànni Twitter rẹ.

O ni pé, ìdílé Gani Fawehinmi àti MKO Abiola nìkan kọ́ lo kú fún ìjọba àwa-ara-wa, atí wipe ó pọn dandan lati bẹ ìdílé awọn akọni fun ijọba tiwantiwa yooku wo pẹ̀lú ìfàmì ẹ̀yẹ̀ dawọn lọ́lá.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àkọlé fídíò,

Abiola: Mínístà Adewole jẹ nínú ànfààní ọ̀la rẹ̀

Sẹnetọ Sani pe awọn ìdílé àwọn ènìyàn wọ̀nyìí pẹ̀lú nílo ìwúrí láti ọ̀dọ̀ ìjọba.

Àkọlé fídíò,

'Mi ò ní wo bọ́ọ̀lù mọ́ ti Nàìjíríà bá fìdírẹmi ni Russia 2018'