Orílẹ̀-èdè mẹ́fà ná-an-tán bí owó lọ́jọ́ kan nínú ìdíje àgbáyé

Image copyright Getty Images
Àkọlé àwòrán Ìkọ agbábọ̀ọ̀lù Uruguay bẹ̀rẹ̀ ìdíje ife-ẹ̀yẹ àgbáyé wọn pẹlú jìjáwé olúborí nínú ìfẹsẹ̀wọnsẹ pẹ̀lú Egypt

Ìkọ agbábọ̀ọ̀lù Uruguay ló kọ́kọ́ na ikọ agbabọọlu Egypt ilẹ Afrika ninu ìdíje ife-ẹ̀yẹ àgbáyé

Jose Gimenez ló fipa gbá bọ́ọ̀lù sáwọ̀n Egypt lẹ́yìn ìsẹ́jú àádọ́run lórí pápá.

Carlos Sanchez lo gba bọọlu fun Jose Gimenez to fi fun àwọn South America ní amì àyo kan ti Uruguay fi gbégbá orókè.

Àbájáde èyí túmọ̀ sí pé Russia ló ń sáájú ní ìsọ̀rí kíní lẹ́yin tí Russia fàgbà han Saudi Arabia pẹ̀lú àmì ayo márùn-ún sódo lọ́jọ́bọ.

Iran náà gbégbá orókè nínú ìfẹsẹ̀wọnsẹ̀ àkọ́kọ́ wọn lẹ́yìn ife ẹ̀yẹ àgbáye ní 1998 bí Aziz Bouhaddouz ti Morocco se gbá bọ́ọ́lù sílé ara wọn ní ìṣéjú márùndílọ́gọ́rún tí ìdíje ti bẹ̀rẹ̀.

ÀWỌN ORILẸ-EDE TO KOJU ARA WỌN ESI IDIJE WỌN
Egypt vs Uruguay 0-1
Iran vs Morocco 1-0
Portugal vs Spain 3-3

Morocco ní orílẹ̀-èdè Afíríkà kejì tó fìdírẹmi nígbà tí ìdíje ti fẹ́ parí nínú ìdíje ife ẹ̀yẹ àgbáyé tó ń lọ lọ́wọ́.

Erin nla meji lo koju ara wọn nigba ti Portugal ati Spain jọ náa tán bi owó ti wọn si pari pelu ami ayo mẹ́ta sí mẹ́ta.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ
Media caption'Mi ò ní wo bọ́ọ̀lù mọ́ ti Nàìjíríà bá fìdírẹmi ni Russia 2018'

Orilẹ-ede Russia ati Saudi Arabia lo kọkọ ṣide idije ife ẹyẹ agbaye tọdun 2018 lọjọbọ to kọja.