'Akọ òkúta ni Super Eagles, ó ń fọ́ ọ̀tá ni'
Àwọn àmúyẹ fun gbígbọ́ orin ko le ṣiṣẹ lori ẹ̀rọ rẹ

Russia 2018: Nàìjíríà dúró gìdìgbà, ki Ọlọrun fún wa ṣe

Àwọn Mikel á fakọyọ lálẹ́ òní nínú ìdíje Nàìjíríà àti Croatia

Ogunmilọrọ Ayọdele to wa ni Moscow bayii wa lára àwọn tó ń ṣàtìlẹyìn fún Super Eagles lọ́wọ́ ni Russia.

Ó gbà pé ikọ agbabọọlù Super Eagles naa to gbangba sùn lọ́yẹ́ laibẹru nitori pe ẹni ti wọn ba kọlu, a mọ pe nkan ki si ẹsẹ̀ ràgó ni.

Ajanaku Nàìjíríà kọja mo ri nkan fìrí, ti a ba ri erin, kí a gbà pé a rí erin.

Naijiria n pade Croatia lalẹ oni laago mẹjọ alẹ nipele akọkọ ti wọn yoo ti kopa ninu idije FIFA 2018 fun ife ẹyẹ agbaye to n lọ lọwọ lorilẹ-ede Russia.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí: